Beth-shan
32.5000, 35.5000 Wo lórí Google Maps
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Beth-shan
Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Aṣtoreti: wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Beti-Ṣani.
Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Saulu, àti òkú àwọn ọmọ bíbí rẹ̀ kúrò lára odi Beti-Ṣani, wọ́n sì wá sí Jabesi, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.
Dafidi sì lọ ó sì kó egungun Saulu, àti egungun Jonatani ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọkùnrin Jabesi Gileadi, àwọn tí ó jí wọn kúrò ní ìta Beti-Ṣani, níbi tí àwọn Filistini gbé so wọ́n rọ̀, nígbà tí àwọn Filistini pa Saulu ní Gilboa.