- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1900–1700 BC
Jacob, Joseph & Egypt
Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Gẹnẹsisi 46:7nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Ó kó àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ obìnrin, gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ lọ sí Ejibiti.
- Gẹnẹsisi 46:8nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Israẹli (Jakọbu àti ìran rẹ̀) tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ Ejibiti: Reubeni àkọ́bí Jakọbu.
- Gẹnẹsisi 46:9nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Reubeni: Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi.
- Gẹnẹsisi 46:10nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Simeoni: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu, tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọbìnrin ará Kenaani.
- Gẹnẹsisi 46:11nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
- Gẹnẹsisi 46:12nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Juda: Eri, Onani, Ṣela, Peresi àti Sera (ṣùgbọ́n Ẹri àti Onani ti kú ní ilẹ̀ Kenaani). Àwọn ọmọ Peresi: Hesroni àti Hamulu.
- Gẹnẹsisi 46:13nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin: Isakari! Tola, Pua, Jaṣibu àti Ṣimroni.
- Gẹnẹsisi 46:14nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Sebuluni: Seredi, Eloni àti Jahaleli.
- Gẹnẹsisi 46:15nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Lea tí ó bí fún Jakọbu ní Padani-Aramu yàtọ̀ fún Dina ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) lápapọ̀.
- Gẹnẹsisi 46:16nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Gadi: Sefoni, Haggi, Ṣuni, Esboni, Eri, Arodi, àti Areli.
- Gẹnẹsisi 46:17nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Aṣeri: Imina, Iṣifa, Iṣfi àti Beriah. Arábìnrin wọn ni Sera. Àwọn ọmọkùnrin Beriah: Heberi àti Malkieli.
- Gẹnẹsisi 46:18nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Jakọbu bí nípasẹ̀ Silipa, ẹni tí Labani fi fún Lea ọmọbìnrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́rìndínlógún lápapọ̀.
- Gẹnẹsisi 46:19nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Rakeli aya Jakọbu: Josẹfu àti Benjamini.
- Gẹnẹsisi 46:20nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Ní Ejibiti, Asenati ọmọbìnrin Potifẹra, alábojútó àti àlùfáà Oni, bí Manase àti Efraimu fún Josẹfu.
- Gẹnẹsisi 46:21nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Benjamini: Bela, Bekeri, Aṣbeli, Gera, Naamani, Ehi, Roṣi, Mupimu, Huppimu àti Ardi.
- Gẹnẹsisi 46:22nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Rakeli bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ mẹ́rìnlá lápapọ̀.
- Gẹnẹsisi 46:23nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Dani: Huṣimu.
- Gẹnẹsisi 46:24nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri, àti Ṣillemu.
- Gẹnẹsisi 46:25nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ tí Biliha ẹni tí Labani fi fún Rakeli ọmọ rẹ̀ bí fún Jakọbu. Wọ́n jẹ́ méje lápapọ̀.
- Gẹnẹsisi 46:26nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn tí ó lọ pẹ̀lú Jakọbu sí Ejibiti, àwọn tí ó jẹ́ ìran rẹ̀ tààrà láìka àwọn aya ọmọ rẹ̀, jẹ́ ènìyàn mẹ́rìndínláàádọ́rin.
- Gẹnẹsisi 46:27nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Josẹfu ní Ejibiti àwọn ará ilé Jakọbu tí ó lọ sí Ejibiti jẹ́ àádọ́rin lápapọ̀.
- Gẹnẹsisi 46:28nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Jakọbu sì rán Juda ṣáájú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Josẹfu, kí wọn bá à le mọ ọ̀nà Goṣeni. Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Goṣeni,
- Gẹnẹsisi 46:29nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Josẹfu tọ́jú kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ ó sì lọ sí Goṣeni láti pàdé Israẹli baba rẹ̀. Bí Josẹfu ti dé iwájú baba rẹ̀, ó dì mọ́ baba rẹ̀ ó sì sọkún fún ìgbà pípẹ́.
- Gẹnẹsisi 46:30nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Israẹli wí fún Josẹfu pé, “Wàyí o, mo le kú, níwọ̀n bí mo ti rí i fún ara mi pé, o wà láààyè síbẹ̀.”
- Gẹnẹsisi 46:31nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti fún àwọn ará ilé baba rẹ̀ pé, “Èmi yóò gòkè lọ, èmi yóò sì bá Farao sọ̀rọ̀, èmi yóò sì wí fún un pé, ‘Àwọn arákùnrin mi àti ìdílé baba mi tí ń gbé ní Kenaani ti tọ̀ mí wá.