Fò sí àkóónú

circa 1900–1700 BC

Jacob, Joseph & Egypt

Jacob wrestles with God and becomes Israel; Joseph is sold into slavery yet rises to save the world from famine.

840 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Gẹnẹsisi 45:10nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Ìwọ yóò gbé ní agbègbè Goṣeni, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní.

  2. Gẹnẹsisi 45:11nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò pèsè fún yín níbẹ̀. Nítorí ó ṣì ku ọdún márùn-ún gbáko ti ìyàn yóò fi mú. Kí ìwọ àti ilé rẹ àti ohun tí í ṣe tìrẹ má ba à di aláìní.

  3. Gẹnẹsisi 45:12nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    “Ẹ̀yin fúnra yín àti Benjamini arákùnrin mi pẹ̀lú rí i pé, lóòótọ́ lóòótọ́, èmi Josẹfu ni mo ń bá a yín sọ̀rọ̀.

  4. Gẹnẹsisi 45:13nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Ẹ sọ fún baba mi nípa gbogbo ọlá tí a fún mi ní ilẹ̀ Ejibiti àti ohun gbogbo tí ẹ̀yin ti rí, kí ẹ sì mú baba mi tọ̀ mí wá sí ìhín yìí kíákíá.”

  5. Gẹnẹsisi 45:14nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó dì mọ́ Benjamini arákùnrin rẹ̀, ó sì sọkún, Benjamini náà sì dì mọ́ ọn, pẹ̀lú omijé lójú.

  6. Gẹnẹsisi 45:15nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Ó sì tún fẹnu ko gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ lẹ́nu, ó sì sọkún sí wọn lára. Lẹ́yìn èyí, Josẹfu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀.

  7. Gẹnẹsisi 45:16nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ìròyìn náà dé ààfin Farao pé àwọn arákùnrin Josẹfu dé, inú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀ dùn.

  8. Gẹnẹsisi 45:17nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Farao wí fún Josẹfu pé, “Wí fún àwọn arákùnrin rẹ pé, ‘Èyí ni kí ẹ ṣe, ẹ di ẹrù lé ẹranko yín kí ẹ sì padà sí ilẹ̀ Kenaani,

  9. Gẹnẹsisi 45:18nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    kí ẹ sì mú baba yín àti ìdílé yín tọ̀ mí wá. Èmi yóò fún un yín ní ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sì le è gbádùn ilẹ̀ yìí.’

  10. Gẹnẹsisi 45:19nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    “A pàṣẹ fún ọ láti sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ṣe èyí. ẹ mú kẹ̀kẹ́ ẹrù láti ilẹ̀ Ejibiti fún àwọn ọmọ yín àti àwọn aya yín. Kí ẹ sì mú baba yín tọ mí wá.

  11. Gẹnẹsisi 45:20nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe àníyàn nípa ohun ìní yín nítorí èyí tí ó dára jù nínú ilẹ̀ Ejibiti yóò jẹ́ tiyín.’ ”

  12. Gẹnẹsisi 45:21nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí. Josẹfu fún wọn ni kẹ̀kẹ́ ẹrù bí Farao ti pàṣẹ, ó sì fún wọn ní oúnjẹ fún ìrìnàjò wọn pẹ̀lú.

  13. Gẹnẹsisi 45:22nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Ó fún ẹni kọ̀ọ̀kan wọn ní aṣọ tuntun. Ṣùgbọ́n Benjamini ni ó fún ní ọ̀ọ́dúnrún (300) ẹyọ owó idẹ fàdákà àti ìpààrọ̀ aṣọ márùn-ún.

  14. Gẹnẹsisi 45:23nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó ránṣẹ́ sí baba rẹ̀: kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru àwọn ohun mèremère ilẹ̀ Ejibiti àti abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá tí ó ru ọkà àti oríṣìíríṣìí oúnjẹ.

  15. Gẹnẹsisi 45:24nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó rán àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe ń pínyà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jà ní ọ̀nà o!”

  16. Gẹnẹsisi 45:25nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wá sí ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani.

  17. Gẹnẹsisi 45:26nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Wọn wí fún un pé, “Josẹfu ṣì wà láààyè! Kódà òun ni alákòóso ilẹ̀ Ejibiti.” Ẹnu ya Jakọbu, kò sì gbà wọ́n gbọ́.

  18. Gẹnẹsisi 45:27nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Josẹfu ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Josẹfu fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jakọbu, baba wọn sọ.

  19. Gẹnẹsisi 45:28nǹkan bí 1707 ṣáájú Kristi

    Israẹli sì wí pé, “Mo gbà dájúdájú wí pé, Josẹfu ọmọ mi wà láààyè. Èmi ó lọ rí i kí n tó kú.”

  20. Gẹnẹsisi 46:1nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Israẹli mú ìrìnàjò rẹ̀ pọ̀n pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó ní, nígbà tí ó sì dé Beerṣeba, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run Isaaki baba rẹ̀.

  21. Gẹnẹsisi 46:2nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

  22. Gẹnẹsisi 46:3nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi

    Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀.

  23. Gẹnẹsisi 46:4nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”

  24. Gẹnẹsisi 46:5nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀.

  25. Gẹnẹsisi 46:6nǹkan bí 1706 ṣáájú Kristi

    Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.