Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Strife

158 ẹsẹ · 57 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà.

  2. Mo bẹ̀ yín ẹ̀yin ara, ní orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi, pé kí gbogbo yín fohùn ṣọ̀kan kí ó máa ṣe sí ìyapa láàrín yín, àti pé kí a lè ṣe yín pé ní inú àti ìmọ̀ kan náà.

  3. Ẹ̀yin ará mi, àwọn kan láti ilé Kloe sọ di mí mọ̀ fún mi pé ìjà ń bẹ́ láàrín yín.

  4. Ohun tí mo ń sọ ní pé, olúkúlùkù yín ń wí pé, “Èmí tẹ̀lé Paulu”; “Èmi tẹ̀lé Apollo”; òmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kefa, Peteru”; àti ẹlòmíràn wí pé, “Èmi tẹ̀lé Kristi.”

  5. Ǹjẹ́ a ha pín Kristi bí? Ṣé a kan Paulu mọ́ àgbélébùú fún un yín bí? Ǹjẹ́ a tẹ̀ yín bọ omi ní orúkọ Paulu bí?

  6. Ará, èmí kò sí le bá yín sọ̀rọ̀ bí àwọn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, bí kò ṣe bí àwọn ti í ṣe ti ara, àní bí àwọn ọmọ ọwọ́ nínú Kristi.

  7. Nítorí ẹ̀yin jẹ́ ti ara síbẹ̀. Nítorí, níwọ̀n bí owú jíjẹ àti ìjà ṣe wà láàrín ara yín, ẹ̀yin kò ha ṣe ti ayé bí? Ẹ̀yin kò ha ṣe bí ènìyàn lásán bí?

  8. Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.”

  9. Ẹ kíyèsi i pé, mo ti fi ara mi àti Apollo ṣe àpẹẹrẹ nǹkan tí mo wí, pé kí ẹ̀yin lè ti ipa wa kọ́ láti máa ṣe ohun tí a ti kọ̀wé kọjá. “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe tìtorí ẹnìkan gbéraga sí ẹnìkejì.”

  10. Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

  11. Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́?

  12. Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké wọ̀nyí láàrín ara yín.

  13. Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí.

  14. Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ.

  15. Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́?

  16. Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.

  17. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀?

  18. Ṣùgbọ́n tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí, ohun kan tí mo lè sọ sí gbogbo rẹ̀ ni pé, a kò ní ìlànà tí ó yàtọ̀ sí èyí tí mo ti sọ, pé obìnrin gbọdọ̀ fi gèlè bo orí rẹ̀ nígbà tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ tàbí tí ó bá ń gbàdúrà láàrín ìjọ Ọlọ́run.

  19. Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú.

  20. Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan.

  21. Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere.

  22. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà.

  23. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé sí yín nínú Olúwa pé, ẹ̀yin kì yóò ní èrò ohun mìíràn; ṣùgbọ́n ẹni tí ń yọ yín lẹ́nu yóò ru ìdájọ́ tirẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́.

  24. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń bu ara yín ṣán, tí ẹ sì ń jẹ ara yín run, ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe pa ara yín run.

  25. Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà,