- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Solomon
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó lé nígba (250) àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn.
Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”
Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí Olúwa,
nípa ìlànà ojoojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mose wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àìwúkàrà, ní àjọ ọ̀sẹ̀ méje àti àjọ àgọ́.
Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.
Wọn kò sì yà kúrò nínú àṣẹ ọba sí àwọn àlùfáà tàbí sí àwọn ọmọ Lefi, nínú ohunkóhun, àti pẹ̀lú ti ìṣúra.
Gbogbo iṣẹ́ Solomoni ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé Olúwa sì parí.
Nígbà náà ni Solomoni lọ sí Esioni-Geberi àti Elati ní Edomu létí òkun.
Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó (450) tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá.
Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.
Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún.
Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́,
oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu.
Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni.
Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọjá òkìkí tí mo gbọ́.
Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!
Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”
Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni.
Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.
Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda.
Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.
Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì,
láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni.
Ọba Solomoni sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán asà.
Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún (300) kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún (300) ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni.