Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Solomon: Wealth of

12 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Wealth of

  1. Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba.

  2. Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì wúrà,

  3. láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Arabia, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.

  4. Solomoni ọba sì pọ̀ ní ọrọ̀ àti ní ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba ayé lọ.

  5. Ọba sì jẹ́ kí fàdákà pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti igi kedari ni ó ṣe kí ó dàbí igi sikamore tí ń bẹ ní àfonífojì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  6. Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè.

  7. Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.

  8. Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni.

  9. Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì,

  10. Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá.

  11. Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  12. Mo rò nínú ara mi, “Wò ó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóso Jerusalẹmu síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.”