Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Solomon: Builds idolatrous temples

9 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Builds idolatrous temples

  1. Solomoni ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Farao, àwọn ọmọbìnrin Moabu, àti ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni àti ti àwọn ọmọ Hiti.

  2. Wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀ Solomoni fàmọ́ wọn ní ìfẹ́.

  3. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) obìnrin, àwọn ọmọ ọba àti ọ̀ọ́dúnrún (300) àlè, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà.

  4. Bí Solomoni sì ti di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ sì yí i ní ọkàn padà sí ọlọ́run mìíràn, ọkàn rẹ̀ kò sì ṣe déédé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

  5. Solomoni tọ Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni lẹ́yìn, àti Moleki òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni.

  6. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe búburú níwájú Olúwa; kò sì tọ Olúwa lẹ́yìn ní pípé, bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.

  7. Lórí òkè tí ń bẹ níwájú Jerusalẹmu, Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, òrìṣà ìríra Moabu, àti fún Moleki, òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni.

  8. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo àwọn àjèjì obìnrin rẹ̀, ẹni tí ń sun tùràrí, tí wọ́n sì ń rú ẹbọ fún òrìṣà wọn.

  9. Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Jerusalẹmu ní ìhà gúúsù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Aṣtoreti ọlọ́run ìríra àwọn ará Sidoni, fún Kemoṣi ọlọ́run ìríra àwọn ará Moabu àti fún Moleki, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ammoni.