Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Solomon: Prophecies concerning

17 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Prophecies concerning

  1. Nígbà tí ọjọ́ rẹ bá pé, tí ìwọ ó sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ lékè lẹ́yìn rẹ, èyí tí ó ti inú rẹ jáde wá, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀.

  2. Òun ó sì kọ́ ilé fún orúkọ mi, èmi yóò sì fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ láéláé.

  3. Èmi ó máa ṣe baba fún un, òun yóò sì máa jẹ́ ọmọ mi. Bí òun bá dẹ́ṣẹ̀, èmi yóò sì fi ọ̀pá ènìyàn nà án, àti ìnà àwọn ọmọ ènìyàn.

  4. Ṣùgbọ́n àánú mi kì yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú un kúrò lọ́dọ̀ Saulu, tí èmi ti mú kúrò níwájú rẹ.

  5. A ó sì fi ìdílé rẹ àti ìjọba rẹ múlẹ̀ níwájú rẹ títí láé, a ó sì fi ìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ títí láé.’ ”

  6. Olúwa bínú sí Solomoni nítorí ọkàn rẹ̀ ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó ti fi ara hàn án lẹ́ẹ̀méjì.

  7. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kìlọ̀ fún Solomoni kí ó má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, ṣùgbọ́n Solomoni kò pa àṣẹ Olúwa mọ́.

  8. Nítorí náà Olúwa wí fún Solomoni pé, “Nítorí bí ìwọ ti ṣe nǹkan yìí, tí ìwọ kò sì pa májẹ̀mú mi àti àṣẹ mi mọ́, tí mo ti pàṣẹ fún ọ, dájúdájú èmi yóò fa ìjọba ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, èmi yóò sì fi fún ẹlòmíràn.

  9. Ṣùgbọ́n, nítorí Dafidi baba rẹ, Èmi kì yóò ṣe é ní ọjọ́ rẹ. Èmi yóò fà á ya kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ.

  10. Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jerusalẹmu tí èmi ti yàn.”

  11. nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀.

  12. Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé.

  13. Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀.

  14. Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

  15. Ó wí fún mi pé, Solomoni ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a rẹ̀.

  16. Èmi yóò fi ìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.

  17. Olúwa ti búra nítòótọ́ fún Dafidi, Òun kì yóò yípadà kúrò nínú rẹ̀, nínú irú-ọmọ inú rẹ ni èmi ó gbé kalẹ̀ sí orí ìtẹ́ rẹ.