Skip to content

Zadok

40 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Zadok

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé.

  2. Sì wò ó, Sadoku pẹ̀lú àti gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ń ru àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà sọ̀kalẹ̀; Abiatari sí gòkè, títí gbogbo àwọn ènìyàn sì fi dẹ́kun àti máa kọjá láti ìlú wá.

  3. Ọba sì wí fún Sadoku pé, “Sì tún gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà padà sí ìlú, bí èmi bá rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa, yóò sì tún mú mi padà wá, yóò sì fi àpótí ẹ̀rí náà hàn mí àti ibùgbé rẹ̀.

  4. Ọba sì wí fún Sadoku àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Ahimasi ọmọ rẹ, àti Jonatani ọmọ Abiatari.

  5. Sadoku àti Abiatari sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run padà sí Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé ibẹ̀.

  6. Ṣé Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀? Yóò sì ṣe, ohunkóhun tí ìwọ bá gbọ́ láti ilé ọba wá, ìwọ ó sì sọ fún Sadoku àti Abiatari àwọn àlùfáà.

  7. Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Ahimasi ọmọ Sadoku, àti Jonatani ọmọ Abiatari; láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yin ó sì rán ohunkóhun tí ẹ̀yin bá gbọ́ sí mi.”

  8. Huṣai sì wí fún Sadoku àti fún Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Báyìí ni Ahitofeli ti bá Absalomu àti àwọn àgbàgbà Israẹli dámọ̀ràn, báyìí lèmi sì bá a dámọ̀ràn.

  9. Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

  10. Ahimasi ọmọ Sadoku sì tún wí fún Joabu pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tọ Kuṣi lẹ́yìn.” Joabu sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìròyìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.”

  11. Alóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáré ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Ahimasi ọmọ Sadoku.” Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìyìnrere wá!”

  12. Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀.

  13. Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé; Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.

  14. Ṣùgbọ́n Sadoku àlùfáà, Benaiah ọmọ Jehoiada, Natani wòlíì, Ṣimei àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Rei àti olórí ogun Dafidi ni kò darapọ̀ mọ́ Adonijah.

  15. Ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́ rẹ, àti Sadoku àlùfáà, àti Benaiah ọmọ Jehoiada, àti Solomoni ìránṣẹ́ rẹ ni kò pè.

  16. Dafidi ọba sì wí pé, “Ẹ pe Sadoku àlùfáà wọlé fún mi àti Natani wòlíì àti Benaiah ọmọ Jehoiada.” Nígbà tí wọ́n wá síwájú ọba,

  17. Níbẹ̀ ni Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì yóò ti fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli. Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, ‘Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!’

  18. Nígbà náà ni Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada, àwọn ará Kereti àti Peleti sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Solomoni gun ìbáaka Dafidi ọba wá sí Gihoni.

  19. Sadoku àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Solomoni lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!”

  20. Ọba sì ti rán Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada àti àwọn ará Kereti àti Peleti pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbáaka ọba,

  21. Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gihoni. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́.

  22. Ọba sì fi Benaiah ọmọ Jehoiada jẹ olórí ogun ní ipò Joabu àti Sadoku àlùfáà ní ipò Abiatari.

  23. Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀: Asariah ọmọ Sadoku àlùfáà:

  24. Benaiah ọmọ Jehoiada ni olórí ogun; Sadoku àti Abiatari ni àwọn àlùfáà;

  25. Ahitubu baba Sadoku, Sadoku baba Ahimasi,