Skip to content

Ahimaaz

13 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ahimaaz

  1. Ọba sì wí fún Sadoku àlùfáà pé, “Aríran ha kọ́ ni ọ́? Padà sí ìlú ní àlàáfíà, àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì pẹ̀lú rẹ, Ahimasi ọmọ rẹ, àti Jonatani ọmọ Abiatari.

  2. Wò ó, àwọn ọmọ wọn méjèèjì sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, Ahimasi ọmọ Sadoku, àti Jonatani ọmọ Abiatari; láti ọwọ́ wọn ni ẹ̀yin ó sì rán ohunkóhun tí ẹ̀yin bá gbọ́ sí mi.”

  3. Jonatani àti Ahimasi sì dúró ní En-Rogeli ọ̀dọ́mọdébìnrin kan sì lọ, ó sì sọ fún wọn, wọ́n sì lọ wọ́n sọ fún Dafidi ọba nítorí pé kí a má bá à rí wọn pé wọ́n wọ ìlú.

  4. Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì tọ obìnrin náà wá sí ilé náà, wọ́n sì béèrè pé, “Níbo ni Ahimasi àti Jonatani gbé wà?” Obìnrin náà sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gòkè rékọjá ìṣàn odò náà.” Wọ́n sì wá wọn kiri, wọn kò sì rí wọn, wọ́n sì yípadà sí Jerusalẹmu.

  5. Ahimasi ọmọ Sadoku sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìròyìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

  6. Ahimasi ọmọ Sadoku sì tún wí fún Joabu pé, “Jọ̀wọ́, bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré tọ Kuṣi lẹ́yìn.” Joabu sì bi í pé, “Nítorí kín ni ìwọ ó ṣe sáré, ọmọ mi, ìwọ kò ri pé kò sí ìròyìn rere kan tí ìwọ ó mú lọ.”

  7. Ó sì wí pé, “Bí ó ti wù kí ó rí, èmi ó sáré.” Ó sì wí fún un pé, “Sáré!” Ahimasi sì sáré ní ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀, ó sì sáré kọjá Kuṣi.

  8. Alóre náà sì wí pé, “Èmi wo ìsáré ẹni tí ó wà níwájú ó dàbí ìsáré Ahimasi ọmọ Sadoku.” Ọba sì wí pé, “Ènìyàn re ni, ó sì ń mú ìyìnrere wá!”

  9. Ahimasi sì dé, ó sì wí fún ọba pé, “Àlàáfíà!” Ó sì wólẹ̀ fún ọba, ó dojúbolẹ̀ ó sì wí pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó fi àwọn ọkùnrin tí ó gbé ọwọ́ wọn sókè sí olúwa mi ọba lé ọ lọ́wọ́.”

  10. Ọba sì béèrè pé, “Àlàáfíà ha wà fún Absalomu, ọmọdékùnrin náà bí?” Ahimasi sì dáhùn pé, “Nígbà tí Joabu rán ìránṣẹ́ ọba, àti èmi ìránṣẹ́ rẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ìdí rẹ̀.”

  11. Ahitubu baba Sadoku, Sadoku baba Ahimasi,

  12. Ahimasi baba Asariah, Asariah baba Johanani,

  13. Sadoku ọmọ rẹ̀ àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.