Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ahitub

13 ẹsẹ · 4 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. lára wọn ni Ahijah, tí ó wọ efodu. Òun ni ọmọ arákùnrin Ikabodu Ahitubu, ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, àlùfáà Olúwa ní Ṣilo kò sí ẹni tí ó mọ̀ pé Jonatani ti lọ.

  2. Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu.

  3. Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba.

  4. Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.” Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.”

  5. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu tí a ń pè ní Abiatari sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dafidi lọ.

  6. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé.

  7. Ahitubu baba Sadoku, Sadoku baba Ahimasi,

  8. Asariah baba Amariah Amariah baba Ahitubu

  9. Ahitubu baba Sadoku. Sadoku baba Ṣallumu,

  10. Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;

  11. Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣafṣa jẹ́ akọ̀wé;

  12. àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

  13. Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run,