Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prudence

192 ẹsẹ · 40 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́, ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.

  2. Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.

  3. Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.

  4. Má ṣe wà nínú àwọn tí ń ṣe ìgbọ̀nwọ́, tàbí nínú àwọn tí ó dúró fún gbèsè.

  5. Bí ìwọ kò bá ní nǹkan tí ìwọ ó fi san, nítorí kín ni yóò ṣe gba ẹni rẹ kúrò lábẹ́ rẹ?

  6. Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.

  7. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.

  8. Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀: nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

  9. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè; nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

  10. Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà: nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

  11. Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára; lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

  12. Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́?

  13. Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ,

  14. àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́ orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé.

  15. Má ṣe dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ pẹ̀lú yóò dàbí i rẹ̀.

  16. Dá aláìgbọ́n lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ̀.

  17. Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fi ara pamọ́ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n rí, kàkà kí ó dúró ó tẹ̀síwájú, ó sì jìyà rẹ̀.

  18. Àwọn ẹlẹ́yà a máa ru ìlú sókè, ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn máa ń mú ìbínú kúrò.

  19. Aláìgbọ́n ènìyàn fi gbogbo ẹnu rẹ̀ bínú ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa kó ìbínú rẹ̀ ní ìjánu.

  20. Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á; nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.

  21. A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀

  22. Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?

  23. Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè, èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé

  24. Mo sọ wí pé, pa òfin ọba mọ́, nítorí pé, ìwọ ti ṣe ìbúra níwájú Ọlọ́run.

  25. Má ṣe jẹ́ kí ojú kán ọ láti kúrò ní iwájú ọba, má ṣe dúró nínú ohun búburú, nítorí yóò ṣe ohunkóhun tí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn.