Skip to content

Gate

4 verses

31.7700, 35.2300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Gate

  1. Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.

  2. Ibodè àfonífojì ni Hanuni àti àwọn ará Sanoa tún mọ. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan ìgbọ̀nwọ́ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.

  3. Ẹnu ibodè Ààtàn ni Malkiah ọmọ Rekabu, alákòóso agbègbè Beti-Hakeremu tún mọ. Ó tún un mọ, ó sì gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀, àwọn ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè rẹ̀ sí ààyè wọn.

  4. Mo sì tún yan àwọn olórí Juda láti gun orí odi náà. Mo sì tún yan àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì láti dúpẹ́. Àwọn kan yóò gòkè odi lọ sí apá ọ̀tún sí ọ̀nà ibodè Ààtàn.