Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prudence: Exemplified by Christ

12 ẹsẹ · 40 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Exemplified by Christ

  1. Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n; òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga a ó sì gbé e lékè gidigidi.

  2. Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.

  3. Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.” Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’

  4. Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ”

  5. Nítorí náà wọ́n sì dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.

  6. Nígbà náà ni àwọn Farisi péjọpọ̀ láti ronú ọ̀nà tì wọn yóò gbà fi ọ̀rọ̀ ẹnu mú un.

  7. Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olóòtítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

  8. Nísinsin yìí sọ fún wa, kí ni èrò rẹ? Ǹjẹ́ ó tọ́ láti san owó orí fún Kesari tàbí kò tọ́?”

  9. Ṣùgbọ́n Jesu ti mọ èrò búburú inú wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dán mi wò?

  10. Ẹ fi owó ẹyọ tí a fi ń san owó orí kan hàn mi.” Wọn mú dínárì kan wá fún un,

  11. ó sì bi wọ́n pé, “Àwòrán ta ni èyí? Àkọlé tà sì ní?”

  12. Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Kesari ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Kesari fún Kesari, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”