Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murmuring

170 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?

  2. Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún, tí Ọlọ́run sì ṣọgbà dí mọ́ ká?

  3. Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi; ìkérora mi sì tú jáde bí omi.

  4. Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.

  5. Èmi wà láìní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyàbalẹ̀, bí kò ṣe ìdààmú.”

  6. Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ? Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?

  7. Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri, kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.

  8. Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

  9. “Kíyèsi i, nínú èyí ìwọ ṣìnà! Èmi ó dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!

  10. Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń bá a jà, wí pé, òun kò ní sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?

  11. Nítorí pe ó fi ìṣọ̀tẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ó pàtẹ́wọ́ ní àárín wa, ó sì sọ ọ̀rọ̀ odi púpọ̀ sí Ọlọ́run.”

  12. Ti Dafidi. Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀;

  13. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá, Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.

  14. Ìwọ ti bá wa jà, ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa, àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa, wọ́n sì fi ipá gba oko wa.

  15. Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn, Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.

  16. Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

  17. Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

  18. Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.

  19. Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

  20. nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.

  21. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.

  22. Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.

  23. Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá, ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú, tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

  24. Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

  25. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?