Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murmuring

170 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òun ìbá ta òróró ìkunra yìí ju owó iṣẹ́ ọdún kan lọ, kí ó sì fi owó rẹ̀ ta àwọn tálákà lọ́rẹ.” Báyìí ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ gún obìnrin náà lára.

  2. Ṣùgbọ́n àwọn Farisi, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pe, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ̀lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

  3. Àwọn kan nínú àwọn Farisi sì wí fún wọn pé, “Ki lo de tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”

  4. Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

  5. Àti àwọn Farisi àti àwọn akọ̀wé ń kùn pé, “Ọkùnrin yìí ń gba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì ń bá wọn jẹun.”

  6. Ó sì dáhùn ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Wò ó, láti ọdún mélòó wọ̀nyí ni èmi ti ń sìn ọ́, èmi kò sì rú òfin rẹ rí, ìwọ kò sì tí ì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi, láti fi bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣe àríyá.

  7. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tí ó fi panṣágà fi ọrọ̀ rẹ̀ ṣòfò, ìwọ sì ti pa ẹgbọrọ màlúù àbọ́pa fún un.’

  8. Nígbà tí wọ́n sì rí i, gbogbo wọn ń kùn, wí pé, “Ó lọ bá ọkùnrin ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ní àlejò.”

  9. Nígbà náà ni àwọn Júù ń kùn sí i, nítorí tí ó wí pé, “Èmi ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá.”

  10. Wọ́n sì wí pé, “Jesu ha kọ́ èyí, ọmọ Josẹfu, baba àti ìyá ẹni tí àwa mọ̀? Báwo ni ó ṣe wí pé, ‘Èmi ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá’?”

  11. Nítorí náà Jesu dáhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrín yín!

  12. Nítorí náà ni àwọn Júù ṣe ń bá ara wọn jiyàn, pé, “Ọkùnrin yìí yóò ti ṣe lè fi ara rẹ̀ fún wa láti jẹ?”

  13. Nígbà tí Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn sí ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Èyí jẹ́ ìkọ̀sẹ̀ fún yín bí?

  14. Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́.

  15. Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?”

  16. Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ”

  17. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.

  18. Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn.

  19. Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.

  20. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní àwọn ti ń kùn, àwọn aláròyé, ti ń rìn nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn; wọn ń gbéraga nípa ara wọn, wọ́n sì ń ṣátá àwọn ènìyàn mìíràn fún èrè ara wọn.