Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murmuring

170 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé,

  2. “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ìjọ ènìyàn búburú yìí yóò fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi.

  3. Sọ fún wọn, bí mo ti wà láààyè nítòótọ́ ni Olúwa wí, gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ wí létí mi ni èmi ó ṣe fún un yín.

  4. Nínú aginjù yìí ni ẹ ó kú sí, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn láti ọmọ ogún ọdún ó lé àní gbogbo ẹ̀yin tí a kà.

  5. Ọ̀kan nínú yín kò ní í dé ilẹ̀ tí mo búra nípa ìgbọ́wọ́sókè láti fi ṣe ibùgbé yín, bí kò ṣe Kalebu ọmọ Jefunne àti Joṣua ọmọ Nuni.

  6. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ yín tí ẹ wí pé wọn ó di ìjẹ, àwọn ni n ó mú dé bẹ̀ láti gbádùn ilẹ̀ tí ẹ kọ̀sílẹ̀.

  7. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, òkú yín yóò ṣubú ní aginjù yìí.

  8. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín yóò sì máa rin kiri nínú aginjù fun ogójì ọdún wọn ó máa jìyà nítorí àìnígbàgbọ́ yín, títí tí ọkàn gbogbo yín yóò fi ṣòfò tán ní aginjù.

  9. Fún ogójì ọdún èyí jẹ́ ọdún kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nínú ogójì ọjọ́ tí ẹ fi yẹ ilẹ̀ náà wò ẹ̀yin ó sì jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì mọ bí ó ti rí láti lòdì sí mi.

  10. Èmi, Olúwa, lo sọ bẹ́ẹ̀; Èmi ó sì ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí ìjọ ènìyàn búburú yìí tí wọ́n kó ra wọn jọ lòdì sí mi. Nínú aginjù yìí ni òpin yóò dé bá wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò kú sí.”

  11. Àwọn ọkùnrin tí Mose rán láti yẹ ilẹ̀ wò, tí wọ́n sì mú gbogbo ìjọ kùn sí i nípa ìròyìn búburú tí wọ́n mú wá nípa ilẹ̀ náà;

  12. Olúwa sì kọlu àwọn ọkùnrin tó mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà, àjàkálẹ̀-ààrùn sì pa wọ́n níwájú Olúwa.

  13. Wọ́n sì dìde sí Mose, pẹ̀lú àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli, ìjòyè nínú ìjọ, àwọn olórúkọ nínú àjọ, àwọn ọkùnrin olókìkí.

  14. Wọ́n kó ara wọn jọ láti tako Mose àti Aaroni, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ti kọjá ààyè yín, ó tó gẹ́ẹ́! Mímọ́ ni gbogbo ènìyàn, kò sí ẹni tí kò mọ́ láàrín wọn, Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, nítorí kí wá ni ẹ̀yin ṣe gbé ara yín ga ju ìjọ ènìyàn Olúwa lọ?”

  15. Kò ha tó gẹ́ẹ́ pé o ti mú wa jáde láti ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin láti pa wá sínú aginjù yìí? O tún wá fẹ́ sọ ara rẹ di olúwa lé wa lórí bí?

  16. Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò sì tí ì mú wa dé ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì pín ilẹ̀ ìní àti ọgbà àjàrà. Ìwọ ha fẹ́ sọ wá di ẹrú bí? Rárá o, àwa kì yóò gòkè wá!”

  17. Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kùn sí Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn Olúwa.”

  18. “Yàgò kúrò láàrín ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojúbolẹ̀.

  19. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú Olúwa ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.”

  20. Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú ọ̀pá Aaroni padà wá síwájú ẹ̀rí, láti fi pamọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì fún àwọn ọlọ̀tẹ̀. Èyí ó sì mú òpin bá kíkùn sínú wọn sí mi, kí wọn kí ó má ba à kú.”

  21. Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti páláṣẹ fún un.

  22. Omi kò sí fún ìjọ ènìyàn, àwọn ènìyàn sì kó ara wọn jọ pọ̀ sí Mose àti Aaroni,

  23. wọ́n bá Mose jà wọ́n sì wí pé, “Ìbá kúkú sàn kí a kú nígbà tí àwọn arákùnrin ti kú níwájú Olúwa!

  24. Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí?

  25. wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”