Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions

106 ẹsẹ · 21 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.

  2. Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.

  3. Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;

  4. àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.

  5. Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

  6. “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi, mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

  7. Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.

  8. Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.

  9. Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

  10. Ibú omi ń pe ibú omi nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀ gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀.

  11. Ìwọ mú wa wá sínú ẹ̀wọ̀n o sì di ẹrù lé ẹ̀yìn wa.

  12. Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

  13. Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè

  14. Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà.

  15. Ìwọ ti fi oúnjẹ bọ́ wọn ìwọ ti mú wọn wa ẹkún mu ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.

  16. “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀ tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.

  17. Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́ tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,

  18. nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò; àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;

  19. Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé,

  20. Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa.

  21. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n, síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  22. Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn,

  23. ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.

  24. Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn ó mú wọn rí àánú.

  25. Èmi mọ, Olúwa, nítorí òfin rẹ òdodo ni, àti ní òtítọ́ ni ìwọ pọ́n mi lójú.