Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions: Often severe

14 ẹsẹ · 21 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Often severe

  1. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara; ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.

  2. Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.

  3. Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.

  4. Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.

  5. Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.

  6. Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;

  7. àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.

  8. Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

  9. “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi, mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

  10. Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.

  11. Ibú omi ń pe ibú omi nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀ gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀.

  12. Ìwọ mú àwọn ènìyàn gún wá ní orí àwa la iná àti omi kọjá ṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.

  13. Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi.

  14. Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà.