Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 31:41nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose fi ìdá náà fún Eleasari, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

  2. Numeri 31:42nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Israẹli, tí Mose yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun.

  3. Numeri 31:43nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ààbọ̀ tí ìjọ jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn,

  4. Numeri 31:44nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) màlúù

  5. Numeri 31:45nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500).

  6. Numeri 31:46nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000).

  7. Numeri 31:47nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Israẹli, Mose yan ọ̀kan lára àádọ́ta ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Lefi, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.

  8. Numeri 31:48nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú àwọn olórí tí ó wà lórí ẹgbẹẹgbẹ̀rin ogun náà, àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wá sọ́dọ̀ Mose.

  9. Numeri 31:49nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì sọ fún un pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ti ka àwọn ọmọ-ogun náà tí ó wà lábẹ́ ìtọ́jú wa, kò sì sí ọ̀kọ̀ọ̀kan tó dín.

  10. Numeri 31:50nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà làwa ṣe mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, gbogbo ọrẹ wíwà tí a ní, wúrà, ẹ̀wọ̀n, àti júfù, àti òrùka-àmi, àti òrùka etí, àti ìlẹ̀kẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ọkàn an wa níwájú Olúwa.”

  11. Numeri 31:51nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose àti Eleasari àlùfáà, gba wúrà náà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun iṣẹ́ ọ̀ṣọ́.

  12. Numeri 31:52nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Gbogbo wúrà tí àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún mú wá fún Mose àti Eleasari, èyí tí ó jẹ́ ẹbọ ìgbésókè fún Olúwa jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó lé àádọ́ta (16,750) ṣékélì.

  13. Numeri 31:53nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nítorí ológun kọ̀ọ̀kan ti kó ẹrù fún ara rẹ̀.

  14. Numeri 31:54nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose àti Eleasari àlùfáà gba wúrà náà lọ́wọ́ àwọn balógun ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti lọ́wọ́ balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún wọ́n sì ko wá sínú àgọ́ ìpàdé fún ìrántí àwọn Israẹli níwájú Olúwa.

  15. Numeri 32:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, tí wọ́n ní ẹran ọ̀sìn àti ohun ọ̀sìn rí wí pé ilẹ̀ Jaseri àti Gileadi dára fún ohun ọ̀sìn.

  16. Numeri 32:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Gadi àti àwọn ọmọ Reubeni sì wá, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Eleasari àlùfáà àti sí olórí gbogbo ìlú, wọ́n sì wí pé,

  17. Numeri 32:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “Atarotu, Diboni, Jaseri, Nimra, Heṣboni, Eleale, Sebamu, Nebo, àti Beoni.

  18. Numeri 32:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ni ilẹ̀ tí Olúwa ti ṣẹ́gun níwájú ìjọ Israẹli tí ó sì dára fún ohun ọ̀sìn, ṣáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì ní ohun ọ̀sìn.”

  19. Numeri 32:5nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ́n wí pé, “Tí a bá rí ojúrere rẹ, jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní. Má ṣe jẹ́ kí a rékọjá odò Jordani.”

  20. Numeri 32:6nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose sọ fún àwọn ọmọ Gadi àti fún ọmọ Reubeni pé, “Ṣé kí àwọn arákùnrin yín lọ sí ogun, kí ẹ̀yin kí ó sì jókòó sí bí?

  21. Numeri 32:7nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kí ni ó dé tí o fi mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israẹli láti lọ sí ibi ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn?

  22. Numeri 32:8nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Èyí ni nǹkan tí baba yín ṣe nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-Barnea láti lọ wo ilẹ̀ náà.

  23. Numeri 32:9nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ sí àfonífojì Eṣkolu tí wọ́n rí ilẹ̀ náà, wọ́n mú ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israẹli láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa ti fi fún wọn.

  24. Numeri 32:10nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ìbínú Olúwa sì dìde sí wọn ní ọjọ́ náà, ó sì búra, wí pé,

  25. Numeri 32:11nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ‘Nítorí wọn kò tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, kì í ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí ó jẹ́ ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó gòkè láti Ejibiti ni yóò rí ilẹ̀ tí mo pinnu gẹ́gẹ́ bí ìbúra fún Abrahamu, fún Isaaki àti fún Jakọbu: