circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 31:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu, àwọn ní ó ṣe okùnfà yíyí àwọn ọ̀mọ̀ Israẹli padà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa nínú èyí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Peori, níbi tí àjàkálẹ̀-ààrùn ti kọlu ìjọ Olúwa.
- Numeri 31:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, pa gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó ti súnmọ́ ọkùnrin,
- Numeri 31:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ṣùgbọ́n kí o dá obìnrin tí kò bá tí ì súnmọ́ ọkùnrin sí fún ara yín.
- Numeri 31:19nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti pa ènìyàn tàbí fọwọ́ kan ẹni tí a pa gbọdọ̀ dúró ní ìta ibùdó àgọ́ fún ọjọ́ méje. Ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje ẹ gbọdọ̀ ya ara yín àti ẹni tí ẹ kó lẹ́rú sí mímọ́.
- Numeri 31:20nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Kí ẹ̀yin kí ó ya aṣọ yín sí mímọ́ àti gbogbo ohun tí a fi awọ ṣe àti gbogbo iṣẹ́ irun ewúrẹ́ àti ohun tí a fi igi ṣe.”
- Numeri 31:21nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Eleasari àlùfáà sì wí fún àwọn olórí ogun náà pé, “Èyí ní ìlànà òfin tí Olúwa fi lélẹ̀ ní àṣẹ fún Mose.
- Numeri 31:22nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Kìkì i wúrà, fàdákà, idẹ, irin, idẹ àti òjé.
- Numeri 31:23nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ohunkóhun tí ó lè la iná ni kí ẹ̀yin ó mú la iná, nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n ẹ yóò fi omi ìyàsímímọ́ sọ ọ́ di mímọ́. Àti gbogbo ohun tí kò lè la iná kọjá ni kí a mú la inú omi.
- Numeri 31:24nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ keje, ẹ fọ aṣọ yín, ẹ̀yin yóò sì mọ́, nígbà náà ní ẹ̀yin yóò lè wọ inú ibùdó àjọ.”
- Numeri 31:25nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Numeri 31:26nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ìwọ àti Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí ilé baba ìjọ ni kí o ka iye àwọn ènìyàn àti ẹranko tí a kó ní ìgbèkùn.
- Numeri 31:27nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Pín ohun ìní àti ìkógun náà láàrín àwọn ọmọ-ogun náà tí ó kópa nínú ogun náà àti láàrín gbogbo ìjọ.
- Numeri 31:28nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Kí o sì gba ìdá ti Olúwa lọ́wọ́ àwọn ológun tí wọn jáde lọ sí ogun náà, ọ̀kan nínú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) nínú àwọn ènìyàn àti nínú màlúù àti nínú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti nínú agbo ẹran.
- Numeri 31:29nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Gba ìdá yìí lára ààbọ̀ ìpín tiwọn, kí o sì fún Eleasari àlùfáà, fún ẹbọ ìgbésókè Olúwa.
- Numeri 31:30nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Lára ààbọ̀ ti Israẹli, yan ọ̀kan kúrò nínú àádọ́ta, yálà ènìyàn, ẹran ọ̀sìn, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn, ewúrẹ́ tàbí ẹ̀yà ẹranko mìíràn. Kó wọn fún àwọn Lefi, tí ó dúró fún olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.”
- Numeri 31:31nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Mose àti Eleasari àlùfáà ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
- Numeri 31:32nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Èrè tí ó kù lára ìkógun tí àwọn ọmọ-ogun kó jẹ́, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675,000) àgùntàn.
- Numeri 31:33nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ẹgbàá méjìléláàádọ́rin (72,000) màlúù
- Numeri 31:34nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rin (61,000) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
- Numeri 31:35nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
pẹ̀lú obìnrin ẹgbàá mẹ́rìndínlógún (32,000), ni kò ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí.
- Numeri 31:36nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ìpín ààbọ̀ àwọn tí ó jáde lọ sí ogun sì jẹ́: ẹgbàá méjìdínláàádọ́sàn-án ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn.
- Numeri 31:37nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (675) àgùntàn;
- Numeri 31:38nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ẹgbọrọ màlúù jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún (36,000), tí ìdá Olúwa sì jẹ́ méjìléláàádọ́rin (72);
- Numeri 31:39nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (30,500), tí ìdá ti Olúwa sì jẹ́ mọ́kànlélọ́gọ́ta (61).
- Numeri 31:40nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ (16,000) ìdá ti Olúwa sì jẹ́ méjìlélọ́gbọ̀n (32).