Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 29:22nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu.

  2. Numeri 29:23nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kẹrin, pèsè akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù.

  3. Numeri 29:24nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti akọ màlúù, àgbò àti àgùntàn, pèsè ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

  4. Numeri 29:25nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  5. Numeri 29:26nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, pèsè akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan, tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.

  6. Numeri 29:27nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn sí ìlànà.

  7. Numeri 29:28nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  8. Numeri 29:29nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kẹfà, pèsè akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò ọlọ́dún kan tí gbogbo rẹ̀ kò ní àbùkù.

  9. Numeri 29:30nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

  10. Numeri 29:31nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  11. Numeri 29:32nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àti ní ọjọ́ keje, pèsè akọ màlúù méje, àgbò méjì, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọlọ́dún kan, tí gbogbo rẹ̀ kò sì ní àbùkù.

  12. Numeri 29:33nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

  13. Numeri 29:34nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà, pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  14. Numeri 29:35nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ kí ẹ̀yin kó ní àpéjọ, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

  15. Numeri 29:36nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kí ẹ̀yin ṣe ìgbékalẹ̀ ẹbọ tí a fi iná ṣe tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ sísun ti akọ màlúù kan, àgbò ọlọ́dún kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan méje, gbogbo rẹ̀ tí kò ní àbùkù.

  16. Numeri 29:37nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti ọ̀dọ́-àgùntàn, pèsè fún wọn ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

  17. Numeri 29:38nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  18. Numeri 29:39nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ yín, àti ẹbọ àtinúwá yín, kí ẹ̀yin kí o pèsè fún Olúwa ní àjọ̀dún tí a yàn yín, ẹbọ sísun, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ohun mímu àti ẹbọ ìkẹ́gbẹ́ yín.’ ”

  19. Numeri 29:40nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli gbogbo ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

  20. Numeri 30:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ fún olórí àwọn ẹ̀yà ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ,

  21. Numeri 30:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    nígbà tí ọkùnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀ ní ìdè kí òun má bà ba ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sọ.

  22. Numeri 30:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “Nígbà tí ọmọbìnrin kan bá sì wà ní ilé baba rẹ̀ tó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa tàbí búra láti fi de ara rẹ̀

  23. Numeri 30:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    tí baba rẹ̀ bá sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ìdè rẹ̀ tí kò sì sọ nǹkan kan sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ kí ó dúró àti gbogbo ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ yóò sì dúró.

  24. Numeri 30:5nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n tí baba rẹ̀ bá kọ̀ fun un ní ọjọ́ tí ó gbọ́, kò sí ọ̀kan nínú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí nínú ìdè tí ó fi de ara rẹ̀ tí yóò dúró; Olúwa yóò sì tú u sílẹ̀ nítorí baba rẹ̀ kọ̀ fún un.

  25. Numeri 30:6nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “Tí ó bá sì ní ọkọ lẹ́yìn ìgbà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ tàbí lẹ́yìn ìgbà tí ó sọ ọ̀rọ̀ kan láti ẹnu rẹ̀ jáde nínú èyí tí ó fi de ara rẹ̀ ní ìdè,