Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 28:28nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan akọ màlúù ní kí ẹ rú ẹbọ ohun mímu ìdámẹ́ta pẹ̀lú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò pẹ̀lú àgbò kan.

  2. Numeri 28:29nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn méje, kí ó jẹ́ ìdákan nínú mẹ́wàá.

  3. Numeri 28:30nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ẹ fi òbúkọ kan ṣe ètùtù fún ara yín.

  4. Numeri 28:31nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kí ẹ̀yin kí ó rú wọn pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu yín àti ẹbọ ohun jíjẹ yín. Kí ẹ sì ri dájú pé àwọn ẹranko náà jẹ́ aláìlábùkù.

  5. Numeri 29:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfùnpè ni ó jẹ́ fún yín.

  6. Numeri 29:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun.

  7. Numeri 29:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdá méjì nínú mẹ́wàá, òsùwọ̀n fún àgbò kan,

  8. Numeri 29:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    àti ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n fún ọ̀dọ́-àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn méje.

  9. Numeri 29:5nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún yín.

  10. Numeri 29:6nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú ẹbọ sísun oṣù àti ẹbọ ohun jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ẹbọ mímu wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà wọn. Fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.

  11. Numeri 29:7nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kẹwàá nínú oṣù keje, kí ẹ ṣe àpéjọ mímọ́. Kí ẹ̀yin kí ó sẹ́ ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

  12. Numeri 29:8nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kí ẹ̀yin kí ó rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí Olúwa, ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kan, kí wọn kí ó sì jẹ́ aláìlábùkù fún yín.

  13. Numeri 29:9nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ màlúù, pèsè ọrẹ ìdámẹ́wàá mẹ́ta, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò àti ìdámẹ́wàá méjì òsùwọ̀n fún àgbò kan,

  14. Numeri 29:10nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n.

  15. Numeri 29:11nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ ewúrẹ́ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù àti ẹbọ sísun gbogbo ìgbà àti ẹbọ jíjẹ rẹ̀ àti ẹbọ mímu wọn.

  16. Numeri 29:12nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe àjọyọ̀ fún Olúwa fún ọjọ́ méje.

  17. Numeri 29:13nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Kí ẹ sì rú ẹbọ sísun kan, ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí ó ní òórùn dídùn sí Olúwa, ẹbọ tí ẹgbọrọ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá tí ó jẹ́ ọdún kan, tí gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ aláìlábùkù.

  18. Numeri 29:14nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun tí a fi òróró pò, ìdámẹ́wàá mẹ́ta òsùwọ̀n fún akọ màlúù kan, bẹ́ẹ̀ ni fún akọ màlúù mẹ́tẹ̀ẹ̀tàlá, ìdámẹ́wàá méjì òsùwọ̀n fún àgbò kan, bẹ́ẹ̀ ni fún àgbò méjèèjì,

  19. Numeri 29:15nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    àti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀dọ́-àgùntàn kan. Bẹ́ẹ̀ ni fún ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rẹ̀ẹ̀rìnlá.

  20. Numeri 29:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti akọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà ẹbọ ohun jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu rẹ̀.

  21. Numeri 29:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Àti ní ọjọ́ kejì ni kí ẹ̀yin kí ó fi ẹgbọrọ akọ màlúù méjìlá, àgbò méjì àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́rìnlá ọlọ́dún kan aláìlábùkù rú ẹbọ.

  22. Numeri 29:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú fún akọ màlúù, fún àgbò, àti fún ọ̀dọ́-àgùntàn kí ẹ pe ẹbọ ohun jíjẹ, àti ẹbọ ohun mímu, kí ó jẹ́ bí iye wọn, gẹ́gẹ́ bí ìlànà.

  23. Numeri 29:19nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun gbogbo ìgbà pẹ̀lú ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ ohun mímu.

  24. Numeri 29:20nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “ ‘Ní ọjọ́ kẹta, pèsè akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì, akọ àgùntàn mẹ́rìnlá ti ọdún kan tí kò ní àbùkù.

  25. Numeri 29:21nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Pẹ̀lú akọ màlúù, àgbò, àti akọ àgùntàn, pèsè ọrẹ ohun jíjẹ àti ohun mímu gẹ́gẹ́ bí iye wọn.