circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 32:37nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Reubeni sì kọ́ Heṣboni, Eleale, Kiriataimu,
- Numeri 32:38nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
pẹ̀lú Nebo pẹ̀lú Baali-Meoni (wọ́n pàrọ̀ orúkọ wọn) àti Sibma. Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.
- Numeri 32:39nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase lọ sí Gileadi, wọ́n sì lé àwọn ọmọ Amori tí ó wà níbẹ̀.
- Numeri 32:40nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Mose sì fi àwọn ọmọ Gileadi fún àwọn ọmọ Makiri àwọn ìran Manase, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.
- Numeri 32:41nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Jairi, ọmọ Manase gba ibùjókòó wọn, ó sì pè wọ́n ní Haffotu Jairi.
- Numeri 32:42nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Noba gba Kenati àti àwọn ìtẹ̀dó rẹ̀, ó sì pè é ní Noba lẹ́yìn orúkọ ara rẹ̀.
Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Ejibiti jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mose àti Aaroni.
Mose sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa, wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.
Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti.
Tí wọ́n sì ń sin gbogbo àkọ́bí wọn, ẹni tí Olúwa ti gbé lulẹ̀ láàrín wọn; nítorí tí Olúwa ti mú ẹ̀san wá sórí àwọn òrìṣà wọn.
Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti.
Wọ́n kúrò ní Sukkoti, wọ́n sì pàgọ́ sí Etamu, ní ẹ̀bá aginjù.
Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli.
Wọ́n sì dìde láti lọ kúrò ní iwájú Pi-Hahirotu, wọ́n sì la àárín òkun kọjá lọ sí aginjù. Wọ́n sì rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta ní aginjù Etamu, wọ́n sì pàgọ́ sí Mara.
Wọ́n kúrò ní Mara wọ́n sì lọ sí Elimu, níbi tí orísun omi méjìlá àti igi ọ̀pẹ àádọ́rin gbé wà, wọ́n sì pàgọ́ níbẹ̀.
Wọ́n kúrò ní Elimu wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun Pupa.
Wọ́n kúrò ní ẹ̀bá Òkun Pupa wọ́n sì pàgọ́ sínú aginjù Sini.
Wọ́n kúrò nínú aginjù Sini wọ́n sì pàgọ́ sí aginjù Dofka.
Wọ́n kúrò ní Dofka wọ́n sì pàgọ́ ní Aluṣi.
Wọ́n kúrò ní Aluṣi wọ́n sì pàgọ́ ní Refidimu níbi tí kò sí omi fún àwọn ènìyàn náà láti mu.
Wọ́n kúrò ní Refidimu wọ́n sì pàgọ́ ní aginjù Sinai.
Wọ́n kúrò ní aginjù Sinai wọ́n sì pàgọ́ ní Kibirotu-Hattaafa.
Wọ́n kúrò ní Kibirotu-Hattaafa wọ́n sì pàgọ́ ní Haserotu.
Wọ́n kúrò ní Haserotu wọ́n sì pàgọ́ ní Ritma.
Wọ́n kúrò ní Ritma wọ́n sì pàgọ́ ní Rimoni-Peresi.