Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 26:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì máa gbàdúrà kí ẹ̀yin má ba à bọ́ sínú ìdẹwò. Nítorí ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.”

  2. Matiu 26:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí ago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá bí kò ṣe pé mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”

  3. Matiu 26:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó tún padà dé sọ́dọ̀ wọn, Ó rí i pé wọn ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun.

  4. Matiu 26:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ó fi wọn sílẹ̀ ó tún padà lọ láti gbàdúrà nígbà kẹta, ó ń wí ohun kan náà.

  5. Matiu 26:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ó tọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó wí pé, “Àbí ẹ̀yin sì ń sùn síbẹ̀, ti ẹ sì ń sinmi? Wò ó wákàtí náà tí dé ti a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.

  6. Matiu 26:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ dìde! Ẹ jẹ́ kí a máa lọ! Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mi hàn ń bọ̀ wá!”

  7. Matiu 26:47nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà Júù wá.

  8. Matiu 26:48nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi àmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.”

  9. Matiu 26:49nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nísinsin yìí, Judasi wá tààrà sọ́dọ̀ Jesu, ó wí pé, “Àlàáfíà, Rabbi!” Ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

  10. Matiu 26:50nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí pé, “Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá.” Àwọn ìyókù sì sún síwájú wọ́n sì mú Jesu.

  11. Matiu 26:51nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì sá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.

  12. Matiu 26:52nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni a ó fi idà pa.

  13. Matiu 26:53nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì angẹli méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

  14. Matiu 26:54nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsin yìí?”

  15. Matiu 26:55nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.

  16. Matiu 26:56nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ.

  17. Matiu 26:57nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí.

  18. Matiu 26:58nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu.

  19. Matiu 26:59nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un.

  20. Matiu 26:60nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan. Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde.

  21. Matiu 26:61nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Èmi lágbára láti wó tẹmpili Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ”

  22. Matiu 26:62nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ń kọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?”

  23. Matiu 26:63nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́. Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè, kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”

  24. Matiu 26:64nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”

  25. Matiu 26:65nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?”