circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Matiu 25:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu?
- Matiu 25:38nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́?
- Matiu 25:39nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’
- Matiu 25:40nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni.’
- Matiu 25:41nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀.
- Matiu 25:42nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu.
- Matiu 25:43nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’
- Matiu 25:44nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’
- Matiu 25:45nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi, ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’
- Matiu 25:46nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”
- Matiu 26:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé,
- Matiu 26:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”
- Matiu 26:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa.
- Matiu 26:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á.
- Matiu 26:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”
- Matiu 26:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Jesu wà ní Betani ní ilé ọkùnrin tí à ń pè ní Simoni adẹ́tẹ̀.
- Matiu 26:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Bí ó ti ń jẹun, obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú alabasita òróró ìkunra iyebíye, ó sì dà á sí i lórí.
- Matiu 26:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rí i, inú bí wọn. Wọ́n wí pé, “Irú ìfowóṣòfò wo ni èyí?
- Matiu 26:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èéha ti ṣe, obìnrin yìí ìbá tà á ní owó púpọ̀, kí a sì fi owó náà fún àwọn aláìní.”
- Matiu 26:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu ti mọ èrò ọkàn wọn, ó wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń dá obìnrin yìí lẹ́bi? Ó ṣe ohun tí ó dára fún mi.
- Matiu 26:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ẹ̀yin yóò ní àwọn aláìní láàrín yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n, ẹ̀yin kò le rí mi nígbà gbogbo.
- Matiu 26:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nípa dída òróró ìkunra yìí sí mi lára, òun ń ṣe èyí fún ìsìnkú mi ni.
- Matiu 26:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, a ó sì máa ṣe ìrántí rẹ̀ nígbà gbogbo fún ìṣesí rẹ̀ yìí. Níbikíbi tí a bá ti wàásù ìyìnrere yìí ní gbogbo àgbáyé ni a ó ti sọ ìtàn ohun tí obìnrin yìí ṣe.”
- Matiu 26:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn aposteli méjìlá ti à ń pè ní Judasi Iskariotu lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.
- Matiu 26:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Òun sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin yóò san fún mi bí mo bá fi Jesu lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n sì fún un ní ọgbọ́n owó fàdákà. Ó sì gbà á.