Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 25:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’

  2. Matiu 25:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ Ènìyàn yóò dé.

  3. Matiu 25:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

  4. Matiu 25:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ǹtì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀.

  5. Matiu 25:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn.

  6. Matiu 25:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.

  7. Matiu 25:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.

  8. Matiu 25:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn ṣírò owó rẹ̀.

  9. Matiu 25:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘Olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’

  10. Matiu 25:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  11. Matiu 25:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’

  12. Matiu 25:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  13. Matiu 25:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí.

  14. Matiu 25:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Èmi bẹ̀rù, mo sì lọ pa tálẹ́ǹtì rẹ mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, nǹkan rẹ nìyìí.’

  15. Matiu 25:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kójọ níbi tí èmi kò fọ́nká ká sí.

  16. Matiu 25:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ìwọ ìbá kúkú fi owó mi sí ilé ìfowópamọ́ tí èmi bá dé èmi ìbá le gba owó mi pẹ̀lú èrè.

  17. Matiu 25:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá.

  18. Matiu 25:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní.

  19. Matiu 25:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’

  20. Matiu 25:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run.

  21. Matiu 25:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́.

  22. Matiu 25:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì.

  23. Matiu 25:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

  24. Matiu 25:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín.

  25. Matiu 25:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’