Fò sí àkóónú

circa 6 BC – AD 30

The Life of Jesus

The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.

3,779 ẹsẹ · 4 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Matiu 24:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forítì í dópin ni a ó gbàlà.

  2. Matiu 24:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    A ó sì wàásù ìyìnrere nípa ìjọba náà yìí ní gbogbo ayé ká, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.

  3. Matiu 24:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),

  4. Matiu 24:16nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.

  5. Matiu 24:17nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀.

  6. Matiu 24:18nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn.

  7. Matiu 24:19nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì!

  8. Matiu 24:20nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi.

  9. Matiu 24:21nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.

  10. Matiu 24:22nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú.

  11. Matiu 24:23nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́.

  12. Matiu 24:24nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ.

  13. Matiu 24:25nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.

  14. Matiu 24:26nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní, ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá,” ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́.

  15. Matiu 24:27nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.

  16. Matiu 24:28nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ibikíbi tí òkú bá gbé wà, ibẹ̀ ni àwọn ẹyẹ igún ń kójọpọ̀ sí.

  17. Matiu 24:29nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Lójúkan náà, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’

  18. Matiu 24:30nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nígbà náà ni àmì Ọmọ Ènìyàn yóò sì fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.

  19. Matiu 24:31nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Yóò sì rán àwọn angẹli rẹ̀ jáde pẹ̀lú ohùn ìpè ńlá, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé àti ọ̀run jọ.

  20. Matiu 24:32nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Nísinsin yìí, ẹ kọ́ òwe lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nígbà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti ń yọ tuntun tí ó bá sì ń ru ewé, ẹ̀yin mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn súnmọ́ tòsí.

  21. Matiu 24:33nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí ẹ̀yin bá sì rí i tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bá ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìpadàbọ̀ mi dé tán lẹ́yìn ìlẹ̀kùn.

  22. Matiu 24:34nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ìran yìí kì yóò kọjá títí tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ.

  23. Matiu 24:35nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Ọ̀run àti ayé yóò rékọjá, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ mi kì yóò rékọjá.

  24. Matiu 24:36nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.

  25. Matiu 24:37nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí.