circa 6 BC – AD 30
The Life of Jesus
The eternal Son of God enters history: born in Bethlehem, baptized in the Jordan, crucified at Golgotha, raised on the third day.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Matiu 26:66nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ki ni ẹ ti rò èyí sí. Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”
- Matiu 26:67nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú.
- Matiu 26:68nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kristi, ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”
- Matiu 26:69nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lákòókò yìí, bí Peteru ti ń jókòó ní àgbàlá, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jesu ti Galili.”
- Matiu 26:70nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”
- Matiu 26:71nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.”
- Matiu 26:72nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”
- Matiu 26:73nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa àmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”
- Matiu 26:74nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.” Lójúkan náà àkùkọ sì kọ.
- Matiu 26:75nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.
- Matiu 27:1nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu.
- Matiu 27:2nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà.
- Matiu 27:3nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù.
- Matiu 27:4nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.” Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”
- Matiu 27:5nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.
- Matiu 27:6nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.”
- Matiu 27:7nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀.
- Matiu 27:8nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní.
- Matiu 27:9nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e.
- Matiu 27:10nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.”
- Matiu 27:11nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”
- Matiu 27:12nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan.
- Matiu 27:13nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?”
- Matiu 27:14nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.
- Matiu 27:15nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi
Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni.