circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 8:2nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.
- Jeremiah 8:3nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
- Jeremiah 8:4nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí?
- Jeremiah 8:5nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti yípadà.
- Jeremiah 8:6nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
- Jeremiah 8:7nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́.
- Jeremiah 8:8nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n, nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn.
- Jeremiah 8:9nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn. Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa, irú ọgbọ́n wo ló kù tí wọ́n ní?
- Jeremiah 8:10nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹlòmíràn. Láti èyí tó kéré jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.
- Jeremiah 8:11nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀. “Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí, nígbà tí kò sí àlàáfíà.
- Jeremiah 8:12nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú, a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò, ni Olúwa wí.
- Jeremiah 8:13nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò, ni Olúwa wí. Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà. Kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀. Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”
- Jeremiah 8:14nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí? A kó ara wa jọ! Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi kí a sì ṣègbé síbẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé. Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu, nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i.
- Jeremiah 8:15nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Àwa ń retí àlàáfíà kò sí ìre kan, tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá bí kò ṣe ìpayà nìkan.
- Jeremiah 8:16nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀ là ń gbọ́ láti Dani, yíyan àwọn akọ ẹṣin mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì. Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run, gbogbo ohun tó wà níbẹ̀, ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.
- Jeremiah 8:17nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín, paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn, yóò sì bù yín jẹ,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 8:18nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi, rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.
- Jeremiah 8:19nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá: “Olúwa kò ha sí ní Sioni bí? Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?” “Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”
- Jeremiah 8:20nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Ìkórè ti rékọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, síbẹ̀ a kò gbà wá là.”
- Jeremiah 8:21nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú, èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.
- Jeremiah 8:22nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀? Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
- Jeremiah 9:1nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé! Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.
- Jeremiah 9:2nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Háà, èmi ìbá ní ni aginjù ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò, kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn: nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.
- Jeremiah 9:3nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Wọ́n ti pèsè ahọ́n wọn sílẹ̀ bí ọfà láti fi pa irọ́; kì í ṣe nípa òtítọ́ ni wọ́n fi borí ní ilẹ̀ náà. Wọ́n ń lọ láti inú ẹ̀ṣẹ̀ kan sí òmíràn; wọn kò sì náání mi, ní Olúwa wí.
- Jeremiah 9:4nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Ṣọ́ra fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ; má ṣe gbẹ́kẹ̀lé àwọn arákùnrin rẹ. Nítorí pé oníkálùkù arákùnrin jẹ́ atannijẹ, oníkálùkù ọ̀rẹ́ sì jẹ́ abanijẹ́.