circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 9:5nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ọ̀rẹ́ ń dalẹ̀ ọ̀rẹ́. Kò sì ṣí ẹni tó sọ òtítọ́, wọ́n ti kọ́ ahọ́n wọn láti máa purọ́. Wọ́n sọ ara wọn di onírẹ̀wẹ̀sì pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀
- Jeremiah 9:6nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ó ń gbé ní àárín ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti mọ̀ mí nínú ẹ̀tàn wọn,” ni Olúwa wí.
- Jeremiah 9:7nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí: “Wò ó, èmi dán wọn wo; nítorí pé kí ni èmi tún le è ṣe? Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi?
- Jeremiah 9:8nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ahọ́n wọn dàbí ọfà olóró; ó ń sọ ẹ̀tàn. Oníkálùkù sì ń fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò rẹ̀, ní inú ọkàn rẹ̀, ó dẹ tàkúté sílẹ̀.
- Jeremiah 9:9nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n nítorí èyí?” ni Olúwa wí. “Èmi kì yóò ha gbẹ̀san ara mi lórí irú orílẹ̀-èdè yìí bí?”
- Jeremiah 9:10nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì sọkún, pohùnréré ẹkún fún àwọn òkè àti ẹkún ìrora lórí pápá oko aginjù wọ̀n-ọn-nì. Nítorí wọ́n di ahoro, wọn kò sì kọjá ní ibẹ̀. A kò sì gbọ́ igbe ẹran ọ̀sìn. Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ti sálọ, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ẹranko sì ti lọ.
- Jeremiah 9:11nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Èmi yóò sì sọ Jerusalẹmu di òkìtì àlàpà àti ihò àwọn ìkookò. Èmi ó sì sọ ìlú Juda di ahoro tí ẹnikẹ́ni kò sì ní le è gbé.”
- Jeremiah 9:12nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ta ni ẹni náà tí ó ní ọgbọ́n láti mòye nǹkan wọ̀nyí? Ta ni Olúwa ti sọ èyí fún, tí ó sì lè ṣàlàyé rẹ̀? Èéṣe tí ilẹ̀ náà fi ṣègbé bí aginjù, tí ẹnìkankan kò sì le là á kọjá?
- Jeremiah 9:13nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.
- Jeremiah 9:14nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.
- Jeremiah 9:15nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.
- Jeremiah 9:16nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”
- Jeremiah 9:17nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Èyí sì ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Sá à wò ó nísinsin yìí! Ké sí obìnrin ti ń ṣọ̀fọ̀ nì kí ó wá; sì ránṣẹ́ pe àwọn tí ó mòye nínú wọn.
- Jeremiah 9:18nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Jẹ́ kí wọn wá kíákíá, kí wọn wá pohùnréré ẹkún lé wa lórí títí ojú wa yóò fi sàn fún omijé tí omi yóò sì máa sàn àwọn ìpéǹpéjú wa.
- Jeremiah 9:19nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
A gbọ́ igbe ìpohùnréré ẹkún ní Sioni: ‘Àwa ti ṣègbé tó! A gbọdọ̀ fi ilẹ̀ wa sílẹ̀, nítorí pé àwọn ilé wa ti parun.’ ”
- Jeremiah 9:20nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, ẹ̀yin obìnrin ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa; ṣí etí yín sí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ. Kọ́ àwọn ọmọbìnrin yín ní ìpohùnréré ẹkún, kí ẹ sì kọ́ ara yín ní arò.
- Jeremiah 9:21nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ikú ti gba ojú fèrèsé wa wọlé ó sì ti wọ odi alágbára wa ó ti ké àwọn ọmọ kúrò ní àdúgbò àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin kúrò ní gbọ̀ngàn ìta gbangba.
- Jeremiah 9:22nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Sọ pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Òkú àwọn ènìyàn yóò ṣubú bí ààtàn ní oko gbangba àti bí ìbùkúnwọ́ lẹ́yìn olùkórè láìsí ẹnìkankan láti kó wọn jọ.’ ”
- Jeremiah 9:23nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Má ṣe jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yangàn nítorí agbára ọgbọ́n rẹ̀, tàbí alágbára nítorí agbára rẹ̀, tàbí ọlọ́rọ̀ nítorí ọrọ̀ rẹ̀.
- Jeremiah 9:24nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ẹ jẹ́ kí ẹni tí ń ṣògo nípa èyí nì wí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí wí pé, Èmi ni Olúwa tí ń ṣe òtítọ́, ìdájọ́ àti òdodo ní ayé, nínú èyí ni mo ní inú dídùn sí,” Olúwa wí.
- Jeremiah 9:25nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí a kọ ilà fún nínú ara nìkan.
- Jeremiah 9:26nǹkan bí 610 ṣáájú Kristi
Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”
- Jeremiah 10:1nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli.
- Jeremiah 10:2nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí, kí àmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín, nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè.
- Jeremiah 10:3nǹkan bí 607 ṣáájú Kristi
Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn, wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣọ̀nà sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.