Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 26:26nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 26:27nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 26:28nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?”

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 26:29nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.”

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 26:30nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Bernike, àti àwọn tí o bá wọn jókòó,

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 26:31nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn wọ ìyẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.”

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 26:32nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Agrippa sì wí fún Festu pé, “A bà dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ bí ó bá ṣe pe kò ì tí ì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Kesari.”

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 27:1nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Itali, wọn fi Paulu àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Juliusi, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Augustu.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 27:2nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-òkun Adramittiu kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí Òkun Asia, a ṣíkọ̀: Aristarku, ará Makedonia láti Tẹsalonika wà pẹ̀lú wa.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 27:3nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sidoni. Juliusi sì ṣe inú rere sì Paulu, ó sì fún un láààyè kí ó máa tọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ kí wọn le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 27:4nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a sì kúrò níbẹ̀, a lọ lẹ́bàá Saipurọsi, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 27:5nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a ré Òkun Kilikia àti Pamfilia kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mira ti Likia.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 27:6nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Níbẹ̀ ni balógun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-òkun Alekisandiria kan, ti ń lọ sí Itali; ó sì fi wa sínú rẹ̀.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 27:7nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọ̀kánkán Knidu, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láààyè, a ba ẹ̀bá Krete lọ, lọ́kankán Salmoni.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 27:8nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Lasea.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 27:9nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìnàjò wa sì ti léwu gan an nítorí nísinsin yìí àwẹ̀ ti kọjá lọ, Paulu dá ìmọ̀ràn.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 27:10nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.”

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 27:11nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ̀ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Paulu wí lọ.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 27:12nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fonike, tí i ṣe èbúté Krete ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oòrùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oòrùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 27:13nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣe bí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń gba ẹ̀bá Krete lọ.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 27:14nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Eurakuilo fẹ́ lù erékùṣù náà.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 27:15nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-òkun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 27:16nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùṣù kan tí a ń pè Kauda, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjá ààbò.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 27:17nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 27:18nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀.