- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 30–62
The Early Church
Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Ìṣe àwọn Aposteli 27:44nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Àti àwọn ìyókù, òmíràn lórí pátákó, àti òmíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ̀.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:1nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:2nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa. Nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:3nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:4nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.”
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:5nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:6nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì; nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:7nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pubiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:8nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Ó sì ṣe, baba Pubiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:9nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:10nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:11nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí àmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:12nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sirakusi, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:13nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:14nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:15nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígbà tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:16nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:17nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Paulu pe àwọn olórí Júù jọ. Nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti ṣe pé èmi kò ṣe ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, síbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Romu lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerusalẹmu wá.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:18nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:19nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù sọ̀rọ̀ lòdì sí i, èyí sún mí láti fi ọ̀ràn náà lọ Kesari, kì í ṣe pe mo ní ẹ̀sùn kan láti fi kan àwọn ènìyàn mi.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:20nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ nítorí ọ̀ràn yìí ni mo ṣe ránṣẹ́ pè yín, láti rí yín àti láti bá yín sọ̀rọ̀ nítorí pé, nítorí ìrètí Israẹli ni a ṣe fi ẹ̀wọ̀n yìí dè mí.”
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:21nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò rí ìwé gbà láti Judea nítorí rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan nínú àwọn arákùnrin tí ó ti ibẹ̀ wá kò ròyìn, tàbí kí ó sọ̀rọ̀ ibi kan sí ọ.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:22nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n àwa ń fẹ́ gbọ́ lẹ́nu rẹ ohun tí ìwọ rò nítorí bí ó ṣe ti ẹgbẹ́ ìlànà yìí ní, àwa mọ̀ pé, níbi gbogbo ni a ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.”
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:23nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Àwọn fi ẹnu kò lórí ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú Paulu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni ó tọ̀ ọ́ wa ni ilé àgbàwọ̀ rẹ̀; àwọn ẹni tí òun sọ àsọyé ọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún, ó ń yí wọn padà nípa ti Jesu láti inú òfin Mose àti àwọn wòlíì, láti òwúrọ̀ títí ó fi di àṣálẹ́.
- Ìṣe àwọn Aposteli 28:24nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ẹlòmíràn gba ohun tí ó wí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn kò sì gbà á gbọ́.