Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 27:19nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 27:20nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 27:21nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 27:22nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 27:23nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí angẹli Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 27:24nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari. Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 27:25nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 27:26nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.”

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 27:27nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrín Òkun Adria, láàrín ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ funra pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 27:28nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 27:29nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 27:30nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèké kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 27:31nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 27:32nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèké, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 27:33nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 27:34nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò gé kúrò lórí ẹnìkan nínú yín.”

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 27:35nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 27:36nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni gbogbo wọ́n sì dárayá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 27:37nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó dín mẹ́rin (276).

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 27:38nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-òkun náà fúyẹ́, nípa kíkó alikama dà sí omi.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 27:39nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ̀ ni wọ́n gbèrò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 27:40nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú Òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbokùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí Òkun.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 27:41nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí Òkun méjì pàdé, wọn fi orí ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 27:42nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pa àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sálọ.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 27:43nǹkan bí 62 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Paulu là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí Òkun lọ sì ilẹ̀.