Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 7:58nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 7:59nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 7:60nǹkan bí 33 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 8:1nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀. Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 8:2nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ènìyàn olùfọkànsìn kan sì gbé òkú Stefanu lọ sin, wọ́n sì pohùnréré ẹkún kíkan sórí rẹ̀.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 8:3nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Saulu bẹ̀rẹ̀ sí da ìjọ ènìyàn Ọlọ́run rú. Ó ń wọ ilé dé ilé, ó sì ń mú àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó sì ń fi wọn sínú túbú.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 8:4nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn tí wọ́n sì túká lọ sí ibi gbogbo ń wàásù ọ̀rọ̀ náà.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 8:5nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Filipi sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú Samaria, ó ń wàásù Kristi fún wọn.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 8:6nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ìjọ àwọn ènìyàn gbọ́, tí wọn sì rí iṣẹ́ àmì tí Filipi ń ṣe, gbogbo wọn sì fi ọkàn kan fiyèsí ohun tí ó ń sọ.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 8:7nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí àwọn ẹ̀mí àìmọ́ ń kígbe sókè bí wọ́n ti ń jáde kúrò lára àwọn ènìyàn, ọ̀pọ̀ àwọn arọ àti amúnkùn ún ni ó sì gba ìmúláradá.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 8:8nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ayọ̀ púpọ̀ sì wà ni ìlú náà.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 8:9nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan wà, tí a ń pè ní Simoni, tí ó ti máa ń pa idán ní ìlú náà, ó sì mú kí ẹnu ya àwọn ará Samaria. Ó sì máa ń fọ́nnu pé ènìyàn ńlá kan ni òun.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 8:10nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí gbogbo èwe àti àgbà fiyèsí tí wọ́n sì ń bu ọlá fún wí pé, “Ọkùnrin yìí ní agbára Ọlọ́run ti ń jẹ́ ńlá.”

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 8:11nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n bu ọlá fún un, nítorí ọjọ́ pípẹ́ ni ó ti ń pa idán fún ìyàlẹ́nu wọn.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 8:12nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gba Filipi gbọ́ bí ó ti ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run, àti orúkọ Jesu Kristi, a bamitiisi wọn.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 8:13nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Simoni tìkára rẹ̀ sì gbàgbọ́ pẹ̀lú nígbà ti a sì bamitiisi rẹ̀, ó sì tẹ̀síwájú pẹ̀lú Filipi, ó wo iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ agbára tí ń ti ọwọ́ Filipi ṣe, ẹnu sì yà á.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 8:14nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu sí gbọ́ pé àwọn ara Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Peteru àti Johanu sí wọn.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 8:15nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì lọ, wọ́n gbàdúrà fún wọn, kí wọn bá à lè gba Ẹ̀mí Mímọ́,

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 8:16nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    nítorí títí ó fi di ìgbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ kò tí ì bà lé ẹnikẹ́ni nínú wọn; kìkì pè a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa ni.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 8:17nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru àti Johanu gbé ọwọ́ lé wọn, wọn sí gba Ẹ̀mí Mímọ́.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 8:18nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Simoni rí i pé nípa gbígbé ọwọ́ lé ni ni a ń ti ọwọ́ àwọn aposteli fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún ni, ó fi owó lọ̀ wọ́n,

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 8:19nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    ó wí pé, “Ẹ fún èmi náà ni àṣẹ yìí pẹ̀lú, kí ẹnikẹ́ni tí èmi bá gbé ọwọ́ lé lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.”

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 8:20nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn wí pé, “Kí owó rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, nítorí tí ìwọ rò láti fi owó ra ẹ̀bùn Ọlọ́run!

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 8:21nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ìwọ kò ni ipa tàbí ìpín nínú ọ̀ràn yìí, nítorí ọkàn rẹ kò ṣe déédé níwájú Ọlọ́run.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 8:22nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ronúpìwàdà ìwà búburú rẹ yìí, kí ó sì gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run bóyá yóò dárí ète ọkàn rẹ jì ọ́.