Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 9:8nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Saulu sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Damasku.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 9:9nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 9:10nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ọmọ-ẹ̀yìn kan sì wà ní Damasku, tí a ń pè ni Anania! Olúwa sì wí fún un lójúran pé, “Anania!” Ó sì wí pé, “Wò ó, èmi nìyí, Olúwa.”

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 9:11nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Olúwa sì wí fún un pé, “Dìde kí ó sì lọ sí ilé Judasi ní òpópónà Tààrà, kí ó sì béèrè ẹni tí a ń pè ni Saulu, ara Tarsu, sá wò ó, ó ń gbàdúrà.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 9:12nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Òun sì tí ri ọkùnrin kan lójúran ti a ń pè ni Anania, ó wọlé, ó sì fi ọwọ́ lé e, kí ó lè ríran.”

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 9:13nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Anania sì dáhùn wí pé, “Olúwa mo tí gbúròó ọkùnrin yìí lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, gbogbo búburú ti ó ṣe sí àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ ni Jerusalẹmu.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 9:14nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhín yìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 9:15nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Máa lọ; nítorí ohun èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Israẹli.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 9:16nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 9:17nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Anania sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Saulu, ó sì wí pé, “Arákùnrin Saulu, Olúwa ni ó rán mi, Jesu tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ ba à lè ríran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 9:18nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitiisi rẹ̀.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 9:19nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun. Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 9:20nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 9:21nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 9:22nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 9:23nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 9:24nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 9:25nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 9:26nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti Saulu sì de Jerusalẹmu ó pète láti da ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn; gbogbo wọn sì bẹ̀rù rẹ̀, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé ọmọ-ẹ̀yìn kan ni.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 9:27nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Barnaba mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó sì sọ fún wọn bí ó ti rí Olúwa ní ọ̀nà, àti bí ó ti fi ìgboyà wàásù ní Damasku ní orúkọ Jesu.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 9:28nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Saulu sì wà pẹ̀lú wọn, ó ń wọlé, ó sì ń jáde ní Jerusalẹmu. Ó sì ń fi ìgboyà wàásù ni orúkọ Olúwa.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 9:29nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 9:30nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn arákùnrin sì mọ̀, wọ́n mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kesarea, wọ́n sì rán an lọ sí Tarsu.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 9:31nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 9:32nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida.