Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 10:15nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 10:16nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 10:17nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 10:18nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 10:19nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 10:20nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kó ara ró láti bá wọn lọ, nítorí èmi ni ó rán wọn.”

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 10:21nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá, kín ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi wá?”

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 10:22nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì wí pé, “Korneliu balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtítọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ angẹli mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.”

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 10:23nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Peteru pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò. Ní ọjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, díẹ̀ nínú àwọn ti o ti gbàgbọ́ ní Joppa sì bá a lọ pẹ̀lú.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 10:24nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesarea, Korneliu sì ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 10:25nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ṣe bí Peteru ti ń wọlé, Korneliu pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 10:26nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru gbé e dìde, ó ni, “Dìde ènìyàn ni èmi tìkára mi pẹ̀lú.”

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 10:27nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 10:28nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 10:29nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi, ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 10:30nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 10:31nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 10:32nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru; ó wọ̀ ní ilé Simoni aláwọ létí òkun.’

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 10:33nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsin yìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 10:34nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 10:35nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 10:36nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 10:37nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 10:38nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 10:39nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.