Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 9:33nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 9:34nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 9:35nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 9:36nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ọmọ-ẹ̀yìn kan sí wà ní Joppa ti a ń pè ni Tabita (èyí tí ó túmọ̀ sí Dọkasi); obìnrin yìí pọ̀ ni iṣẹ́ oore, àti ìtọrẹ àánú ṣíṣe.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 9:37nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ní àkókò náà ni ó wà nínú àìsàn, ó sì kú, wọ́n sì wẹ òkú rẹ̀, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ sí iyàrá òkè.

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 9:38nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Bí Lida sì ti súnmọ́ Joppa, nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbọ́ pé Peteru wà níbẹ̀, wọ́n rán ọkùnrin méjì sí i láti bẹ̀ ẹ́ pé, “Má ṣe jáfara láti dé ọ̀dọ̀ wa.”

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 9:39nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Peteru sí dìde, ó sì bá wọn lọ. Nígbà tí ó dé, wọ́n mú un lọ sí iyàrá òkè náà, gbogbo àwọn opó sí dúró tì í wọn sọkún, wọ́n sì ń fi ẹ̀wù àti aṣọ tí Dọkasi dá hàn án, nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 9:40nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru ti gbogbo wọn sóde, ó sì kúnlẹ̀, ó sí gbàdúrà; ó sì yípadà sí òkú, ó ní “Tabita, dìde.” Ó sì la ojú rẹ̀, nígbà tí ó sì rí Peteru, ó dìde jókòó.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 9:41nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí i, ó fà á dìde; nígbà tí ó sì pe àwọn ènìyàn mímọ́ àti àwọn opó, ó fi lé wọn lọ́wọ́ láààyè.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 9:42nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 9:43nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó gbé ọjọ́ púpọ̀ ni Joppa ní ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan Simoni oníṣọ̀nà-awọ.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 10:1nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 10:2nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 10:3nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 10:4nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?” Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 10:5nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 10:6nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 10:7nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 10:8nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 10:9nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́,

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 10:10nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun, ó bọ́ sí ojúran.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 10:11nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 10:12nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 10:13nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 10:14nǹkan bí 41 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “Rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”