Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 8:23nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí mo wòye pé, ìwọ wa nínú òróǹró ìkorò, àti ní ìdè ẹ̀ṣẹ̀.”

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 8:24nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà náà ni Simoni dáhùn, ó sì wí pé, “Ẹ gbàdúrà sọ́dọ̀ Olúwa fún mi, kí ọ̀kan nínú ohun tí ẹ̀yin tí sọ má ṣe bá mi.”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 8:25nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn sì ti jẹ́rìí, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Olúwa, Peteru àti Johanu padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì wàásù ìyìnrere ni ìletò púpọ̀ ti àwọn ará Samaria.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 8:26nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.”

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 8:27nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn,

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 8:28nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 8:29nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.”

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 8:30nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?”

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 8:31nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 8:32nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí: “A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa; àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 8:33nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún. Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀? Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.”

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 8:34nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?”

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 8:35nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìyìnrere ti Jesu fún un.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 8:36nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti se ìrìbọmi?”

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 8:37nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    And Philip said, If thou believest with all thine heart, thou mayest. And he answered and said, I believe that Jesus Christ is the Son of God.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 8:38nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 8:39nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú, omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 8:40nǹkan bí 34 lẹ́yìn Kristi

    Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìyìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 9:1nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí èémí ìhalẹ̀ mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ,

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 9:2nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    ó béèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí Sinagọgu tí ń bẹ ní ìlú Damasku pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni ọ̀nà yìí, ìbá à ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerusalẹmu.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 9:3nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súnmọ́ Damasku; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí i ká.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 9:4nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì ṣubú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Saulu, Saulu, èéṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?”

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 9:5nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?” Olúwa sì wí fún pé, “Èmi ni Jesu, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 9:6nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.”

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 9:7nǹkan bí 35 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Saulu lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan.