Fò sí àkóónú

circa 970–930 BC

Solomon & The Temple

Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.

635 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Ọba 5:15nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Solomoni sì ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè,

  2. 1 Ọba 5:16nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà.

  3. 1 Ọba 5:17nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀.

  4. 1 Ọba 5:18nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.

  5. 1 Ọba 6:1nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.

  6. 1 Ọba 6:2nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ilé náà tí Solomoni ọba kọ́ fún Olúwa sì jẹ́ ọgọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gíga.

  7. 1 Ọba 6:3nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ìloro níwájú tẹmpili ilé náà, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rẹ̀, ìbú ilé náà, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti iwájú ilé náà.

  8. 1 Ọba 6:4nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe fèrèsé tí kò fẹ̀ fún ilé náà.

  9. 1 Ọba 6:5nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Lára ògiri ilé náà ni ó bu yàrá yíká; àti tẹmpili àti ibi mímọ́ jùlọ ni ó sì ṣe yàrá yíká.

  10. 1 Ọba 6:6nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Yàrá ìsàlẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní ìbú, ti àárín sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ní ìbú, àti ẹ̀kẹta ìgbọ̀nwọ́ méje sì ni ìbú rẹ̀. Nítorí lóde ilé náà ni ó dín ìgbọ̀nwọ́ kọ̀ọ̀kan káàkiri, kí igi àjà kí ó má ba à wọ inú ògiri ilé náà.

  11. 1 Ọba 6:7nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

  12. 1 Ọba 6:8nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìsàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúúsù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárín, àti láti yàrá àárín bọ́ sínú ẹ̀kẹta.

  13. 1 Ọba 6:9nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó kedari.

  14. 1 Ọba 6:10nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi kedari.

  15. 1 Ọba 6:11nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Solomoni wá wí pé,

  16. 1 Ọba 6:12nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    “Ní ti ilé yìí tí ìwọ ń kọ́ lọ́wọ́, bí ìwọ bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ìwọ sì ṣe ìdájọ́ mi, tí o sì pa òfin mi mọ́ láti máa ṣe wọ́n, Èmi yóò mú ìlérí tí mo ti ṣe fún Dafidi baba rẹ̀ ṣẹ nípa rẹ̀.

  17. 1 Ọba 6:13nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì máa gbé àárín àwọn ọmọ Israẹli, èmi kì ó sì kọ Israẹli ènìyàn mi.”

  18. 1 Ọba 6:14nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀.

  19. 1 Ọba 6:15nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi pákó kedari tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó firi tẹ́ ilẹ̀ ilé náà.

  20. 1 Ọba 6:16nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kedari kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní Ibi Mímọ́ Jùlọ.

  21. 1 Ọba 6:17nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ní iwájú ilé náà, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́.

  22. 1 Ọba 6:18nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Inú ilé náà sì jẹ́ kedari, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ kedari; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.

  23. 1 Ọba 6:19nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa ka ibẹ̀.

  24. 1 Ọba 6:20nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Inú ibi mímọ́ náà sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú, àti ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gíga. Ó sì fi kìkì wúrà bo inú rẹ̀ ó sì fi igi kedari bo pẹpẹ rẹ̀.

  25. 1 Ọba 6:21nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi

    Solomoni sì fi kìkì wúrà bo inú ilé náà, ó sì tan ẹ̀wọ̀n wúrà dé ojú ibi mímọ́ jùlọ, ó sì fi wúrà bò ó.