Fò sí àkóónú

circa 970–930 BC

Solomon & The Temple

Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.

635 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Ọba 3:27nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ọba dáhùn, ó wí pé, “Ẹ fi alààyè ọmọ fún obìnrin àkọ́kọ́. Ẹ má ṣe pa á: òun ni ìyá rẹ̀.”

  2. 1 Ọba 3:28nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí gbogbo Israẹli gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, wọ́n sì bẹ̀rù níwájú ọba, nítorí wọ́n ti rí í pé ó ní ọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti ṣe ìdájọ́.

  3. 1 Ọba 4:1nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Solomoni ọba sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli.

  4. 1 Ọba 4:2nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀: Asariah ọmọ Sadoku àlùfáà:

  5. 1 Ọba 4:3nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Elihorefu àti Ahijah àwọn ọmọ Ṣisa akọ̀wé; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọ̀wé ìlú;

  6. 1 Ọba 4:4nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Benaiah ọmọ Jehoiada ni olórí ogun; Sadoku àti Abiatari ni àwọn àlùfáà;

  7. 1 Ọba 4:5nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Asariah ọmọ Natani ni olórí àwọn agbègbè; Sabudu ọmọ Natani, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;

  8. 1 Ọba 4:6nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Ahiṣari ni olùtọ́jú ààfin; Adoniramu ọmọ Abida ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú.

  9. 1 Ọba 4:7nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Solomoni sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbègbè Israẹli, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.

  10. 1 Ọba 4:8nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Orúkọ wọn ni wọ̀nyí: Bene-Huri ní ìlú olókè Efraimu.

  11. 1 Ọba 4:9nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani;

  12. 1 Ọba 4:10nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Bene-Hesedi, ní Aruboti (tirẹ̀ ni Soko àti gbogbo ilẹ̀ Heferi ń ṣe);

  13. 1 Ọba 4:11nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Bene-Abinadabu, ní Napoti (Dori; òun ni ó fẹ́ Tafati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).

  14. 1 Ọba 4:12nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu.

  15. 1 Ọba 4:13nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi (tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin).

  16. 1 Ọba 4:14nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu

  17. 1 Ọba 4:15nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Ahimasi ní Naftali (ó fẹ́ Basemati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).

  18. 1 Ọba 4:16nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Baana ọmọ Huṣai ní Aṣeri àti ní Aloti;

  19. 1 Ọba 4:17nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Jehoṣafati ọmọ Parua ni ó wà ní Isakari;

  20. 1 Ọba 4:18nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Ṣimei ọmọ Ela ni Benjamini;

  21. 1 Ọba 4:19nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Geberi ọmọ Uri ní Gileadi (orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani). Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.

  22. 1 Ọba 4:20nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn Juda àti ti Israẹli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí Òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.

  23. 1 Ọba 4:21nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

  24. 1 Ọba 4:22nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun,

  25. 1 Ọba 4:23nǹkan bí 1014 ṣáájú Kristi

    Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.