- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 970–930 BC
Solomon & The Temple
Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Kronika 1:1nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni ọmọ Dafidi fìdí ara rẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lórí ìjọba rẹ̀. Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú u rẹ̀, ó sì jẹ́ kí ó ga lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
- 2 Kronika 1:2nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, Solomoni bá gbogbo Israẹli sọ̀rọ̀ sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, sí àwọn adájọ́ àti sí gbogbo àwọn olórí Israẹli, àwọn olórí ìdílé
- 2 Kronika 1:3nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
pẹ̀lú Solomoni, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gibeoni, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pa ní aginjù.
- 2 Kronika 1:4nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, Dafidi ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wá láti Kiriati-Jearimu sí ibi tí ó ti pèsè fún un, nítorí ó ti kọ́ àgọ́ fún un ni Jerusalẹmu.
- 2 Kronika 1:5nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n pẹpẹ idẹ tí Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ṣe wà ní Gibeoni níwájú àgọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Solomoni àti gbogbo àpéjọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níbẹ̀.
- 2 Kronika 1:6nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni gòkè lọ sí ibi pẹpẹ idẹ níwájú Olúwa ní ibi àgọ́ ìpàdé, ó sì rú ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹbọ sísun lórí rẹ̀.
- 2 Kronika 1:7nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọ́run farahàn Solomoni, ó sì wí fún un pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ kí n fún ọ.”
- 2 Kronika 1:8nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni dá Ọlọ́run lóhùn pé, “Ìwọ ti fi àánú ńlá han Dafidi baba mi, ìwọ sì ti fi mí jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
- 2 Kronika 1:9nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run, jẹ́ kí ìlérí rẹ sí baba à mi Dafidi wá sí ìmúṣẹ, nítorí ìwọ ti fi mí jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀.
- 2 Kronika 1:10nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Fún mi ní ọgbọ́n àti ìmọ̀, kí èmi kí ó lè máa wọ ilé kí ń sì máa jáde níwájú ènìyàn wọ̀nyí, nítorí ta ni ó le è ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ tí ó pọ̀ yanturu wọ̀nyí?”
- 2 Kronika 1:11nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run wí fún Solomoni pé, “Níwọ́n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí.
- 2 Kronika 1:12nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nítorí náà, ọgbọ́n àti ìmọ̀ ni a ó fi fún ọ, Èmi yóò sì fún ọ ní ọrọ̀, ọlá àti ọ̀wọ̀, irú èyí tí ọba ti ó wà ṣáájú rẹ kò ní, tí àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ kò sì ní ní irú rẹ̀.”
- 2 Kronika 1:13nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Solomoni sì ti ibi gíga Gibeoni lọ sí Jerusalẹmu láti iwájú àgọ́ ìpàdé. Ó sì jẹ ọba lórí Israẹli.
- 2 Kronika 1:14nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ, ó sì ní ẹgbàáje (1,400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàá mẹ́fà (12,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó kó pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ ogun àti pẹ̀lú rẹ̀ ni Jerusalẹmu.
- 2 Kronika 1:15nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ọba náà ṣe fàdákà àti wúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti wọ́pọ̀ ní Jerusalẹmu bí òkúta, àti kedari ó pọ̀ bí igi sikamore ní àwọn ẹsẹ̀ òkè.
- 2 Kronika 1:16nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Àwọn ẹṣin Solomoni ní a gbà láti ìlú òkèrè Ejibiti àti láti kún ọ̀gbọ̀ oníṣòwò ti ọba ni gba okun náà ní iye kan.
- 2 Kronika 1:17nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Ejibiti. Fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin méjìdínláàádọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hiti àti ti àwọn ará Aramu.
- 2 Kronika 2:1nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀
- 2 Kronika 2:2nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.
- 2 Kronika 2:3nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire: “Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.
- 2 Kronika 2:4nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé.
- 2 Kronika 2:5nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ.
- 2 Kronika 2:6nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run tó ga jùlọ, kò le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa, bí kò ṣe kìkì àti sun ẹbọ sun ẹbọ níwájú rẹ̀?
- 2 Kronika 2:7nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní àwọ̀ ojú ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú iṣẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Juda àti Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí baba à mi Dafidi pèsè.
- 2 Kronika 2:8nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.