Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Patriotism

63 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jerusalẹmu; àwọn tí ó fẹ́ ọ yóò ṣe rere.

  2. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi rẹ̀, àti ìre nínú ààfin rẹ̀.

  3. Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá, kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.

  4. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ. Láti àlàáfíà lára Israẹli.

  5. Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.

  6. Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò, tí ó wà láàrín rẹ̀.

  7. Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá; wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”

  8. Àwa ó ti ṣe kọ orin Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì

  9. Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.

  10. Bí èmi kò bá rántí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo.

  11. Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.

  12. Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò jinlẹ̀. “Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí, nígbà tí kò sí àlàáfíà.

  13. Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú, èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.

  14. Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí? Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀? Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?

  15. Háà! Orí ìbá jẹ́ orísun omi kí ojú mi sì jẹ́ orísun omijé! Èmi yóò sì sọkún tọ̀sán tòru nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.

  16. Háà, èmi ìbá ní ni aginjù ilé àgbàwọ̀ fún àwọn arìnrìn-àjò, kí n ba à lè fi àwọn ènìyàn mi sílẹ̀ kí n sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn: nítorí gbogbo wọn jẹ́ panṣágà àjọ aláìṣòótọ́ ènìyàn.

  17. Rántí, Olúwa, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa; wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

  18. Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò, ilé wa ti di ti àjèjì.

  19. Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba, àwọn ìyá wa ti di opó.

  20. A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu; igi wa di títà fún wa.

  21. Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa; àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

  22. Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.

  23. Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́, àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

  24. Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa, kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

  25. Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa nítorí idà tí ó wà ní aginjù.