Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Night

79 ẹsẹ · 42 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.

  2. Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’ Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.

  3. Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.

  4. Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.

  5. Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.

  6. Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.

  7. Agara ìkérora mi dá mi tán. Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún, mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.

  8. Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé, ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.

  9. Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́; wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.

  10. Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́.

  11. Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.

  12. Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi; èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.

  13. Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú; ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.

  14. mo rántí orin mi ní òru. Èmi ń bá àyà mi sọ̀rọ̀, ọkàn mi sì ń ṣe àwárí jọjọ.

  15. Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru, nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.

  16. Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

  17. Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.

  18. Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

  19. Ojú mi ṣáájú ìṣọ́ òru, nítorí kí èmi lè ṣe àṣàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ.

  20. Orin ìgòkè. Ẹ kíyèsi i, ẹ fi ìbùkún fún Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa, tí ó dúró ní ilé Olúwa ní òru.

  21. Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”

  22. Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.

  23. Ó rí i pé òwò òun pé fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.

  24. Ní orí ibùsùn mi ní òru mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́; mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.

  25. Mo ti sùn ṣùgbọ́n ọkàn mi jí. Gbọ́! Olólùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. “Ṣí i fún mi, arábìnrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, aláìlábàwọ́n mi, orí mi kún fún omi ìrì, irun mi kún fún òtútù òru.”