Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God

662 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí mo bá gbé orí mi ga, ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.

  2. Ìwọ sì tún mu àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi di ọ̀tún ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi; àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.

  3. “Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá? Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.

  4. “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

  5. Tàbí ba ilẹ̀ ayé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ.

  6. Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ Olúwa ni ó ṣe nǹkan yìí?

  7. Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.

  8. Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?

  9. Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún, àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye.

  10. “Ti Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára; òun ló ni ìmọ̀ àti òye.

  11. Kíyèsi i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́; Ó sé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìtúsílẹ̀ kan.

  12. Kíyèsi i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì ṣẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.

  13. Tìrẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun; ẹni tí ń ṣìnà àti ẹni tí ń mú ni ṣìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.

  14. Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòhò a sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

  15. Ó tú ìdè ọba ó sì fi àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

  16. Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòhò ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

  17. Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè.

  18. Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfúrufú, ó sì so ayé rọ̀ ní ojú asán.

  19. Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.

  20. Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.

  21. Ó fi ìdè yí omi òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.

  22. Ọ̀wọ́n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbáwí rẹ̀.

  23. Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi Òkun; nípa òye rẹ̀, ó gé agbéraga sí wẹ́wẹ́.

  24. Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀ṣọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi dá ejò wíwọ́ nì.

  25. Kíyèsi i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”