Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa God

662 ẹsẹ · 46 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.

  2. Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ; bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.

  3. Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’

  4. Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí, èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.

  5. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi, ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?

  6. Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi aró wẹ ọwọ́ mi mọ́,

  7. síbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.

  8. “Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.

  9. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.

  10. Kí ẹnìkan sá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì ṣe dáyà fò mí.

  11. Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó tí dúró tì mí, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.

  12. Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé, má ṣe dá mi lẹ́bi; fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.

  13. Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú?

  14. Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí? Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?

  15. Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn, ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,

  16. tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi, tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

  17. Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú, kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

  18. “Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi. Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.

  19. Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀. Ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?

  20. Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà, ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?

  21. Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí, ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

  22. Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere, ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

  23. “Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ; èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.

  24. Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.

  25. Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi! Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè, èmi dààmú mo si wo ìpọ́njú mi.