Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Edomites

154 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Diṣoni Eseri, àti Diṣani. Àwọn ni olórí ìdílé àwọn ará Hori gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ilẹ̀ Seiri.

  2. Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:

  3. Bela ọmọ Beori jẹ ní Edomu. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.

  4. Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  5. Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  6. Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.

  7. Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  8. Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti, létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  9. Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  10. Nígbà tí Baali-Hanani ọmọ Akbori kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau, orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu.

  11. Àwọn wọ̀nyí ni orúkọ àwọn baálẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Esau jáde wá, ní orúkọ ìdílé wọn, bí ìpínlẹ̀ wọn ti rí: baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti.

  12. Baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni,

  13. baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari,

  14. Magdieli, àti Iramu. Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu, gẹ́gẹ́ bí wọn ti tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí wọ́n gbà. Èyí ni Esau baba àwọn ará Edomu.

  15. Ṣùgbọ́n Edomu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò le gba ibí kọjá; bí ẹ bá dán an wò, a ó dìde ogun sí yín, a ó sì bá yín jà pẹ̀lú idà.”

  16. Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “A ó gba ọ̀nà tóóró, bí àwa tàbí ẹran ọ̀sìn wa bá sì mú lára omi rẹ, a ó san owó rẹ̀. A kàn fẹ́ rìn kọjá lórí ilẹ̀ rẹ ni kò sí nǹkan kan mìíràn tí a fẹ́ ṣe.”

  17. Wọ́n tún dáhùn wí pé, “Ẹ kò lè kọjá.” Nígbà náà ni Edomu jáde wá láti kọjú ìjà sí wọn pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àti alágbára ọmọ-ogun.

  18. Nígbà tí Edomu sì kọ̀ jálẹ̀ láti jẹ́ kí wọn kọjá ní ilẹ̀ wọn, Israẹli yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.

  19. Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Esau; àwọn ará Edomu tí ń gbé ní Seiri. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.

  20. Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí ó ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Seiri fún Esau gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.

  21. Ní àkókò Jehoramu, Edomu ṣọ̀tẹ̀ sí Juda, wọ́n sì gbé ọba tiwọn kalẹ̀.

  22. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoramu lọ sí Sairi pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Edomu sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀síbẹ̀, sá padà lọ ilé.

  23. Títí ó fi di òní, Edomu wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Juda, Libina ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà.

  24. Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọingbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.

  25. Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mose níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”