Skip to content

Eliphaz

8 ẹsẹ · 14 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Eliphaz

  1. Adah bí Elifasi fún Esau, Basemati sì bí Reueli,

  2. Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Esau: Elifasi ọmọ Adah aya Esau àti Reueli, ọmọ Basemati tí í ṣe aya Esau pẹ̀lú.

  3. Àwọn ọmọ Elifasi ni ìwọ̀nyí: Temani, Omari, Sefi, Gatamu, àti Kenasi.

  4. Elifasi ọmọ Esau sì tún ní àlè tí a ń pè ní Timna pẹ̀lú, òun ló bí Amaleki fún un. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọ Adah aya Esau.

  5. Àwọn wọ̀nyí ni olórí nínú àwọn ọmọ Esau: àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, Temani, Omari, Sefi, Kenasi,

  6. Kora, Gatamu àti Amaleki. Àwọn wọ̀nyí ló jẹ́ olórí ìdílé tí ó ti ọ̀dọ̀ Elifasi ní Edomu wá, wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ Adah.

  7. Àwọn ọmọ Esau: Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora.

  8. Àwọn ọmọ Elifasi: Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi; láti Timna: Amaleki.