Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Edomites

154 ẹsẹ · 14 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ejibiti, Juda, Edomu, Ammoni, Moabu àti gbogbo àwọn tí ń gbé ní ọ̀nà jíjìn réré ní aginjù. Nítorí pé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jẹ́ aláìkọlà gbogbo àwọn ará ilé Israẹli sì jẹ́ aláìkọlà ọkàn.”

  2. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìṣèjọba Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, ọ̀rọ̀ yìí tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wí pé.

  3. Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Ṣe àjàgà àti ọ̀pá irin fún ara rẹ, kí o sì fiwé ọrùn rẹ.

  4. Kí o rán ọ̀rọ̀ sí ọba ti Edomu, Moabu, Ammoni, Tire àti Sidoni láti ọwọ́ àwọn ikọ̀ tí ó wá sí Jerusalẹmu sọ́dọ̀ Sedekiah ọba Juda.

  5. Kí o sì pàṣẹ fún wọn láti wí fún àwọn olúwa wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: “Sọ èyí fún àwọn olúwa rẹ.

  6. Pẹ̀lú agbára ńlá mi àti ọwọ́ nínà mi ni Èmi dá ayé, ènìyàn àti ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé, mo sì fún ẹni tí ó wu ọkàn mi.

  7. Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.

  8. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóò máa sìn ín àti àwọn ọmọdọ́mọ rẹ̀ títí ilẹ̀ rẹ yóò fi dé; ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá ni yóò tẹríba fún.

  9. “ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.

  10. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’

  11. Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún un yín èyí tí yóò mú u yín jìnnà réré kúrò ní ilẹ̀ yín; kí Èmi kí ó lè lé yín jáde, kí ẹ̀yin ó sì ṣègbé.

  12. Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

  13. Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

  14. Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani, nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau, ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.

  15. Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá; ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀? Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?

  16. Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò, èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn, nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́.

  17. Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀ èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn. Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”

  18. Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un.

  19. Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”

  20. Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, a rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé, ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.

  21. “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo; ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.

  22. Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ; ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta, tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì; láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,” ni Olúwa wí.

  23. “Edomu yóò di ahoro gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ.

  24. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní Olúwa wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.

  25. “Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”