Skip to content

Teman

6 verses

30.2000, 35.7300 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Teman

  1. Nípa Edomu. Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?

  2. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí Olúwa ní fún Edomu, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde; pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.

  3. nítorí náà báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí pé: Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Edomu èmi yóò sì pa àwọn ènìyàn àti àwọn ẹranko rẹ̀. Èmi yóò fi ṣófo láti Temani dé Dedani yóò ti ipa idà ṣubú.

  4. Èmi yóò rán iná sí orí Temani, tí yóò jó gbogbo ààfin Bosra run.”

  5. A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, ìwọ Temani, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

  6. Ọlọ́run yóò wa láti Temani, ibi mímọ́ jùlọ láti òkè Parani ògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run, ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ.